Ibeere
Njẹ̀ ìyàwó nílò láti tẹríba fun ọkọ rẹ̀?
Idahun
Ìtẹríba jẹ ọ̀rọ̀ tí ó ṣe pàtàkì nípa ti ìgbéyàwó. Èyí ní òkodoro àṣẹ ti Bíbélì: "Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín gẹ́gẹ́ bí fun Oluwa. Nítorípé ọkọ ni iṣe orí aya, gẹ́gẹ́ bí Kristi ti ṣe orí ìjọ rẹ̀: oun sì ni Olùgbàlà ara. Nitorinaa gẹgẹ bi ijọ ti tẹriba fun Kristi, bẹ́ẹ̀ si ni kí àwọn aya ki o máa ṣe sí àwọn ọkọ wọn li ohun gbogbo" (Efesu 5: 22 — 24).
Kó dà kí ẹ̀ṣẹ̀ kí ó tó wọ inú ayé, jíjẹ́ orí ti ọkọ ti wà bíi ìlànà (1Timoteu 2:13). Ádámù li a kọ́ ṣẹ̀dá, a sì ṣẹ̀dá Éfà láti jẹ́ "olùrànlọ́wọ́" fún Ádámù (Jẹnẹsisi 2:18-20). Ọlọ́run ti fi onírúurú àṣẹ lé lẹ̀ nínú ayé: ìjọba láti gbé ìdájọ̀ ró ní àwùjọ àti láti pèsè ààbò; olùṣọ́-àgùntàn láti darí àti láti bọ́ àwọn àgùntàn Ọlọ́run; àwọn ọkọ láti fẹ́ àti láti tọ́jú àwọn ìyàwó wọn; àti àwọn baba láti gba àwọn ọmọ wọn ní ìyànjú. Ní gbogbo ọ̀nà, a nílò ìtẹríba: fún ọmọ onílùú sí ìjọba, agbo sí olùṣọ́-àgùntàn, ìyàwó sí ọkọ, ọmọ sí baba.
Ọ̀rọ̀ Gíríkì, tí a túmọ̀ sí "ìtẹríba," hupotasso, jẹ́ irú ọrọ̀-ìṣe kan tí ó ńtẹ̀síwájú. Èyí túmọ̀ sí wípé títẹríba fún Ọlọ́run, ìjọba, olùṣọ̀-àgùntàn kan, tàbí ọkọ kan kìí ṣe ìṣe tí a ǹṣe ní àkókò kansoso nìkan. Ó jẹ́ ìwà tí ǹtẹ̀sìwájú, tí yóò di ìlànà ti ìhùwásí.
Nì àkọ́kọ́, nítòótọ́, a wá ní ojúṣe láti tẹríba sí Ọlọ́run, èyí sì jẹ́ ọ̀nà kan ṣoṣo tí a lè fi gbọ́ràn si Òun nítòótọ́ (Jakọbu 1:21; 4:7). Àti wípé olúkùlùkù Kristiẹni gbọ́dọ̀ gbé ní ìrẹ̀lẹ̀, ní ìgbaradì láti tẹríba sí àwọn ẹlòmíràn (Efesu 5:21). Ní àkíyèsi sí ìtẹríba láàrín igun ti mọ̀lẹ́bí, 1 Kọ́rinti 11: 2-3, wípé ọkọ náà ní láti tẹríba sí Kristi (gẹ́gẹ́ bí Kristi ṣe ṣe sí Ọlọ́run Baba) kí ìyàwó náà tẹríba sí ọkọ rẹ̀.
Èdè àìyedè púpọ̀ nínú ayé wà lóòní nípa àwọn ojúṣe ti ọkọ àti ìyàwó nínú ìgbeyàwó. Kó dà nígbà tí òye ojúṣe ti bíbélì bá yé wa yékéyéké, ọ̀pọ̀lọpọ̀ yàn láti kọ̀ọ́ ní ojúrere tí a gbà wípé "bíbọ́ lọ́wọ́ àṣẹ" ti obìnrin, pẹ̀lú èsì wípé igun ti mọ̀lẹ́bí yapa sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Kò jẹ́ ìyàlẹ́nu wípé ayé ńkọ ètò ti Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn Ọlọ́run gbọ́dọ̀ fi tayọ̀tayọ̀ ṣe àjọyọ̀ ètò náà.
Ìtẹríba kìí ṣe ọ̀rọ̀ kan tí ó burú. Ìtẹríba kìí ṣe àfihàn fún àìjẹ́-ojúlówo tàbí èyì tí kò niye lórí. Kristi fí ìgbàgbogbo tẹrí ara rẹ̀ ba sí ìfẹ́ ti Baba (Luku 22:42; Johanu 5:30), láì dín kín-ń-kín nínú iye Rẹ̀ kù.
Láti kojú àṣìṣe àlàyé ti ayé nípa ìtẹríba ti ìyàwó sí ọkọ rẹ̀, a gbọ́dọ̀ farabàlẹ̀ ṣe àkíyesì àwọn nǹkan wọ̀nyìí nínú Efesu 5: 22-24: 1) Ìyàwó nílò láti tẹríba fún okùnrin kan (ọkọ rẹ̀), kìí ṣe fún gbogbo ọkùnrin. Àṣẹ láti tẹríba kò gùn dé ipò ti obìnrin nínú àwùjọ l'ápapọ̀. 2) Ìyàwó gbọ́dọ̀ fínúfẹ́dọ̀ tẹríba fún ọkọ rẹ̀ ní ìgbọ́ràn ti ara ẹni sí Jésù Olúwa. Òun ńtẹríba fún ọkọ rẹ̀ nítorí wípé ó fẹ́ràn Jésù. 3) Àpẹẹrẹ ìtẹríba ti ìyàwó jẹ́ bíi tí i ìjọ sí Kristi. 4) Kò sí ohun kan tí a sọ nípa agbára ti ìyàwó, ẹ̀bùn tàbí iye; fún wípé òun ńtẹ́ríba fún ọkọ rẹ̀, kò jásì wípé ó kéré tàbí ò dínkù ni iye ní ọ̀nà k'ọnà. Bákannáà ṣe àkìyèsi wípé kò sì àwọn àmúyẹ kankan, sí àṣẹ láti tẹríba, àyààfi "nínú ohun gbogbo". Nítorí náà ọkọ kò nílò láti ṣe àṣeyọrí nínú ìdánwò t'ógbàrònú tàbí ìdánwò tó gba ọgbọ́n kan, kí ó to dí wípé ìyàwó rẹ̀ tẹríba. Ó lè jẹ́ ọ̀tìtọ́ wípé òun kún ojú òṣùwọ̀n jùú lọ látí darí ìgbéyáwò nì àwọn ọ̀nà púpọ, ṣùgbọ́n ó yàn láti tẹ̀lé àwọn ìlànà ti Olúwa, nípa títẹríba sí ìdarì ti ọkọ rẹ̀. Nípa ṣíṣe èyí ìyàwó tí ó níwà bí ti Ọlọ́run yóò jèrè ọkọ rẹ̀ aláìgbàgbọ́ sí Olúwa "láì sọ̀rọ" nìpa ìhùwà mìmọ́ rẹ̀ nìkan (1 Peteru 3:1).
Ìtẹríba gbọ́dọ̀ jẹ́ ìdáhùn àìfagbáraṣe sí ìdarí tí ó kún fún ìfẹ́. Nígbà tí ọkọ bá fẹ́ràn ìyàwó rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi ti fẹ́ràn ìjọ (Efesu 5: 25 -33), nígbànáà ìtẹríba yóò jẹ́ ìdáhùn àìfagbáraṣe láti ọ̀dọ ìyàwó sí ọk rẹ̀. Ṣùgbọ́n kò níí fi ṣe ìfẹ́ ti ọkọ ní tàbí tí kò ní, a tí paá l'áṣẹ wípé kí ìyàwó kí ó tẹríba "gẹ́gẹ́ bí í fún Olúwa" (ẹsẹ 22). Èyí túmọ̀ sí wípé ìgbọ́ràn rẹ̀, sí Ọlọ́run—títẹ́wọ́gbà ìlànà Rẹ̀—yóò yọrísí ìtẹríba rẹ̀ sí ọkọ rẹ̀. Àfiwé pẹ̀lú "gẹ́gẹ́ bí sí Olúwa" tún rán ìyàwó létí wípé àṣẹ tí ó ga jùlọ wà tí òun ní ojúṣe sí. Ní báyìí òun kò sí lábẹ́ ọ̀ranyàn láti ṣe àìgbọràn sí òfin ènìyàn tàbí òfin ti Ọlọ́run ní orúkọ tí "ìtẹríba" sí ọkọ rẹ̀. Òun ńtẹríba nínú àwọn ohun tí o tọ́ àtí èyí tí ó bá òfín mu àti èyí tí ó bu ọlá fún Ọlọ́run. Nítòótọ́, òun kò "tẹríba" sí ìlòkulò—èyí kò tọ́ tàbí bá òfin mu tàbí bu ọlá fún Ọlọ́run. Láti gbìyànjù láti lo ìlànà "ìtẹríba" látí dá ìlòkulò láre jẹ́ yíyí Ìwé-Mímọ́ po àti láti gbé ibi lárugẹ.
Ìtẹríba ìyàwó sí ọkọ nínú Efesu 5 kò fi ààyè gba ọkọ náà láti jẹ́ aládànìkànjọpọ́n tàbí jẹgàba. Àṣẹ Rẹ̀ ní láti ní ìfẹ́ (ẹsẹ 25), òun sí ní ojúṣe níwájú Ọlọ́run láti mú àṣẹ náà ṣẹ. Ọkọ gbọ́dọ̀ lo àṣẹ rẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n, pẹ̀lú ore-ọ̀fẹ́, àti nìnú ìbẹ̀rù tí Ọlọ́run náà tí òun yóò jíyìn fún.
Nígbà tí ọkọ bá ní ìfẹ́ ìyàwó rẹ̀ bí a tí ní ìfẹ́ ìjọ láti ọ̀dọ Krístì, ìtẹríba kò lè nira. Efesu 5:24 sọ wípé, "Nitorinaa gẹgẹ bi ijọ ti tẹriba fun Kristi, bẹ́ẹ̀ si ni kí àwọn aya ki o máa ṣe sí àwọn ọkọ wọn li ohun gbogbo." Nínú ìgbéyàwó, ìtẹríba jẹ́ ìpò tí a fí ńbọ̀wọ̀ àti ọlá fún ọkọ (wo Efesu 5:33) àti fún píparí ohun tí òun ṣe aláìní. Ó jẹ́ ètò tí ó lọ́gbọ́n ti Ọlọ́run fún bí ìdílé ṣe gbọ́dọ ṣiṣẹ́.
Olùṣàlàyé Bíbélì Matthew Henry kọ̀wé wípé, "Obìnrin ní a mú jáde kúrò ní ìhà ẹ̀gbẹ́ ti Ádámù. A kò mú jáde kúrò nínú orì rẹ̀ láti jọba lórí rẹ̀, tàbí jáde láti inú ẹsẹ̀ rẹ̀ sí títẹ̀mọ́lẹ̀ nípá rẹ̀, ṣùgbọ́n láti ìhà rẹ̀ láti lè báa dọ́gba, lábẹ́ apá rẹ̀ fún ìdábòbò àtì ìtòsí ọkàn rẹ̀, láti lè fẹ." Àkọsílẹ̀ tí ó wáyé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nípa ti àṣẹ sí ọkọ àti ìyàwó ní Efesu 5:19–33 ní nínú kíkún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Àwọn onígbàgbọ́ tí ó kún fún Ẹ̀mí gbọ́dọ̀ jẹ́ olùjọ́sìn (5:19), ẹni tí ó kún fún ọpẹ́ (5:20) àti ní ìwà ìteríba (5:21). Pọ́ọ̀lù wá tẹ̀lé ìlànà èrò yìí lórí ìgbé-ayé tí ó ti kún fún Ẹ̀mí tí ó sì mulò fún àwọn ìyàwó ní àwọn ẹsẹ̀ 22-24. Ìyàwó gbọ́dọ̀ tẹríba fún ọkọ rẹ̀, kìí ṣe nítorí wípé àwọn obìnrin kò péye (Bíbélì kò kọ̀ọ irúfẹ́ nǹkàn báwọ̀n yẹn), ṣùgbọ́n nítorí wípé bí Ọlọ́rún ṣẹ ṣe àgbékalẹ̀ ìbáṣepọ̀ ìgbeyàwó láti ṣiṣẹ́ niyẹn.
English
Njẹ̀ ìyàwó nílò láti tẹríba fun ọkọ rẹ̀?