settings icon
share icon
Ibeere

Kílódé tí àwọn Júù àti Árábù/àwọn Mùsùlìmú ṣe kórira ara wọn?

Idahun


Àkọ́kọ́, ó ṣe pàtàkì láti ni òye wípé kìí ṣe gbogbo àwọn Árábù ni Mùsùlùmí, kìí sì ṣe gbogbo Mùsùlùmí ni àwọn Árábù. Nígbàtí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Árábù jẹ́ Mùsùlùmí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Árábù ni kìí ṣe Mùsùlùmí. Síwájú si, àwọn Mùsùlùmí tí kìí ṣe Árábù èyítí ó láàpẹ́rẹ wà ní àwọn agbégbè bíi Indoneṣia àti Maleṣia ju àwọn Árábù tí wọn jẹ́ Mùsùlùmí lọ. Èkejì, o ṣe pàtàkì láti ráńtí wípé kìí ṣe gbogbo àwọn Árábù ni ó kórira àwọn Júù, kìí ṣe gbogbo àwọn Mùsùlùmí ni ó kórira àwọn Júù, kìí ṣe gbogbo àwọn Júù ni ó kórira àwọn Árábù àti Mùsùlùmí. A ní láti kíyèsára láti yẹra fún fífi ojú burúkú wo àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n, bí a bá ńsọ̀rọ̀ ní gbogbogbò, àwọn Árábù àti Mùsùlùmí kò ní ìfẹ́ sí àwọn Jùú tí wọn kò sì gbà wọ́n gbọ́, àti àwọn náà sí wọn.

Bí àlàyé ti bíbélì kan tí ó yànnàná àìgbọ́ ara ẹni yé yìí, Abráhámù ni a ó tọpasẹ̀ rẹ̀ lọ. Àwọn Jùú jẹ́ àwọn ìran tí ó ti ara Isaaki wá láti ọ̀dọ̀ Abráhámù. Àwọn Árábù jẹ́ àwọn ìran tí ó ti ara Iṣmaili wá láti ọ̀dọ̀ Abráhámù. Pẹ̀lú bí Iṣmaili ṣe jẹ́ ọmọkùnrin ẹrú (Jẹnẹsisi 16:1-16) tí Isaaki sí jẹ́ ọmọkùnrin ìlérí tí yóò jogún àwọn ìbùkún Abráhámù (Jẹnẹsis 21:1-3), ó hàn wípé èdè-àìyedè yóò wà láárìn àwọn ọmọkùnrin méjéèjì. Nítorí Iṣmaili tí ó kẹ́gàn Isaaki (Jẹnẹsisi 21:9), Sarah bá Abráhámù sọ̀rọ̀ láti lé Hagari àti Ismaili lọ (Jẹnẹsisi 21:11-21). Ó ṣeé ṣe wípé èyí fa kíkẹ́gàn Isaaki síwájú si nínú ọkàn Ismaili. Ańgẹ́lì kan sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún Hagari wípé Iṣmaili yóò "gbé ní èdè-àìyedè pẹ̀lú gbogbo àwọn arakùnrin rẹ̀" (Jẹnẹsisi 16:11-12).

Ẹ̀sìn Isilamu, èyí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Árábù ńtẹ̀lé, ti jẹ́ kí ìkórìráa yìí kí ó pọ̀si. Kùránì ní nínú àwọn ìtọ́ni fún àwọn Mùsùlùmí nípa àwọn Júù tí ó tako ra wọn nípa àwọn Júù. Ní ibìkan kan ó ní kí àwọn Mùsùlùmí ṣe àwọn Júù bíi arakùnrin wọn àti ní ibòmírán ó pàṣẹ fún àwọn Mùsùlùmí láti kọlu àwọn Júù tí ó kọ̀ láti yípadà sí Isilamu. Kùránì tún fi nńkan míìrán tí ó tako ara wọn hàn nípa èwo nínú àwọn ọmọ Abráhámù ní ọmọkùnrin ìlérí nítòótọ́. Ìwé Mímọ́ Heberu sọ wípé Isaaki ni. Kùránì sọ wípé Iṣmaili ni. Kùránì sọ wípé Iṣmaili ni Abráhámù fẹ́ẹ̀ lè fi rúbọ sí Olúwa, wípé kìí ṣe Isaaki (ní àtakò sí Jẹnẹsis orí 22). Àríyànjiyàn yìí lórí ẹni tí ó jẹ́ ọmọ ìlérí fikún èdè-àìyedè náà lónìí.

Ṣùgbọ́n, gbòǹgbò ìkorò àtijọ́ láàrín Isaaki àti Iṣmaili kò ṣe àlàyé gbogbo èdè-àìyedè tí ó wà láàrín àwọn Júù àti àwọn Árábù lónìí. Ní òtítọ́. Fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún nínú ìtàn Àwọn orílẹ̀-èdè àarin gbùngbùn Ilà-oorùn, àwọn Jùú àti àwọn Árábù gbé ní àlàáfíà tí kò sì sí nǹkankan láàrín wọn. Ìpìlẹ̀ èdè-àìyedè náà ní orísun ti ìgbàlódé kan nínú. Lẹ́yìn Ogun Gbogbo Àgbáyé Kejì, nígbàtí Àjọ Àpapọ̀ Orílẹ̀-èdè l'ágbàyé fi lára ilẹ̀ Isrẹli fún àwọn Júù ní àkókò yẹn àwọn Árábù (àwọn ti Palẹstina) ni o ńgbé ní ilẹ̀ náà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Árábù f'àáké kọrí lòdì sí kí orílẹ̀-èdè Isrẹli gbé ní orí ilẹ̀ yẹn. Àwọn orílẹ̀-èdè Árábù parapọ̀ tí wọn si kọlu Isrẹli pẹ̀lú ète àti lé wọn jáde kúró ní ilẹ̀ náà, ṣùgbọ́n wọ́n borí àwọn Árábù. Láti ìgbà yẹn, èdè-àìyedè láàrín Isrẹli àti àwọn Árábù aládùgbóò wọn ti pọ̀si. Isrẹli wà lórí ilẹ̀ kékeré kan tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó tóbi jù wọn lọ yí wọn ká bíi Jọdani Siria, Saudi Arebia, Iraki, àti Íjíbítì. Ìwò ti wa ni wípé, ní ìbámu pẹ̀lú bíbélì, Isrẹli ní ẹ̀tọ́ láti wà gẹ́gẹ́ bíi orílẹ̀-èdè lórí ilẹ̀ tí wọn èyítí Ọlọ́run fún àwọn ìran Jakọbu, ọmọ ọmọ Abráhámù. Ní àkókò kannáà, àwa gbàgbọ́ gan an wípé Isrẹli gbọ́dọ̀ wá àlàáfíà kí ó sì bọ̀wọ̀ fún àwọn Árábù aládùgbóò rẹ̀. Orin Dafidi 122:6 sọ wípé, "Gbàdúrà fún àlàáfíà Jerusalemu: àwọn tí ó fẹ́ẹ yóò ṣe rere."

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kílódé tí àwọn Júù àti Árábù/àwọn Mùsùlìmú ṣe kórira ara wọn?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries