Ibeere
Kínni ó ńṣẹlẹ̀ sí àwọn tí kò ní àǹfàní láti gbọ́ nípa Jésù rí? Ṣe Ọlọ́run yóò dá ènìyàn kan tí kò gbọ́ nípa Òun rí lẹ́bi?
Idahun
Gbogbo ènìyàn ni yóò ní láti jíhìn fún Ọlọ́run bóyá wọ́n gbọ́ tàbí wọn kò "gbọ́ nípa Rẹ̀". Bíbélì sọ fún wa wípé Ọlọ́run ti fi Ara Rẹ̀ hàn gedegbe nínú àwọn ohun tí Ó dá (Romù 1:20) àti ní ọkàn àwọn ènìyàn (Oniwaasu 3: 11). Ìṣòrò náà ni wípé ìran ènìyàn kún fún ẹ̀ṣẹ̀; gbogbo wa la kọ ìmọ̀ Ọlọ́run tí a sì ṣe lòdì Síi (Romu 1:21-23). Bí kìì bá ṣe ti ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, a kò bá ti fi wá sílẹ̀ fún ìfẹ́ ọkàn wa, fífiwá sílẹ̀ láti ṣ'àwárí bí ayé yìí ti jẹ́ ìmúlẹ̀mófo láìsí Rẹ̀. Òun máa ńṣe èyí fún àwọn tí wọn ńtẹ́sìwájú láti kọ̀ọ́ (Romu 1:24–32).
Nítòótọ́, kìí kúkú ṣe wípé àwọn kan kò gbọ́ nípa Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, ìṣòro náà ni wípé wọ́n ti kọ̀ ohun tí wọ́n gbọ́ àti àwọn ohun tí ó hàn gedegbe nínú ìṣẹ̀dá. Ìwé Deutteronomi 4:29 wípé, "Níbẹ̀ ni ẹ óo ti wá Olúwa Ọlọ́run yín tí ẹ óo sì rí i, tí ẹ bá wá a tọkàntọkàn pẹlu gbogbo ẹ̀mí yín." Ẹsẹ yìí fi ìlànà pàtàkà yé wa—ẹnikẹ́ni tí ó bá wá Ọlọ́run nítòótọ́ yóò Ri. Bí ẹnìkan bá pòǹgbẹ nítòótọ́ láti mọ Ọlọ́run, Ọlọ́run yóò fi ara Rẹ̀ hàn.
Ìṣòro náà ni wípé "Kò sí ẹni tí òye yé, kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọ́run" (Romu 3:11). Àwọn ènìyàn kọ ìmọ̀ Ọlọ́run tí ó hàn gedegbe nínú ìṣẹ̀da àti l'ọ́kàn wọn, wọ́n wá pinnu láti máa jọ́sìn fún "àwọn òrìsà" tí àwọ́n ṣẹ̀dá. Ìwà òmùgọ̀ ni láti máa jiyàn bóyá ó tọ́ fún Ọlọ́run láti rán ẹni tí kò ní àǹfàní láti gbọ́ nípa Ìhìnrere Kristi lọ sí ọ̀run àpáàdì. Àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ gbà fún Ọlọ́run lórí àwọn ohun tí Ọlọ́run tí fi hàn wọ́n. Bíbélì náà wípé àwọn ènìyàn kọ ìmọ̀ yìí, nítorínáà Ọlọ́run kò jẹ̀bi láti dáwọn lẹ́bi nípa rírán wọn lọsí ọ̀run àpáàdì.
Dípò kí a máa jiyàn nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ si àwọn tí kò gbọ́, àwa gẹ́gẹ́ bíi Kristiẹni kò bà máa ṣe akitiyan láti rí daájú wípé wọn gbọ́. A pè wá láti máa tan ìhìnrere kálẹ̀ ní orílẹ̀-èdè gbogbo. (Matteu 28: 19-20; Iṣe àwọn Apọsteli 1:8). A mọ̀ wípé àwọn ènìyàn kọ ìmọ̀ Ọlọ́run tí a fihàn nínú ìṣẹ̀da, èyí sì gbọ́dọ́ ru wá lọ́kàn sókè láti máa kéde ìhìnrere ìgbàlà nípa Jésù Kristi. Gbígba ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nípa Jésù Kristi nìkan soso ni ọ̀nà fún ènìyàn láti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ìyàpa ayérayé kúrò l'ọ́dọ̀ Ọlọ́run.
Bí a lérò wípé àwọn tí kò ní àǹfàní láti gbọ́ ìhìnrere yóò ri àánú Ọlọ́run gbà, àwa yóò kó sí ìṣòro ńlá. Bí a bá gba àwọn tí kò gbọ́ ìhìnrere rí là, ó kúkú sàn kí á má kéde ìhìnrere fún ẹnikẹ́ni. Ohun tí o búrú jùlọ tí a lè ṣe ni wípé kí á wàásù ìhìnrere fún ènìyàn kí á sì jẹ́ kí ò kọ̀ọ́. Bí ìyẹn bá ṣẹlẹ̀, a o dàá ẹni náà lẹ́bi. Àwọn ènìyàn tí kò gbọ́ gbọ́dọ̀ gba idàlẹ́bi, bí bẹ̀ẹ́kọ́, kò ní sì ìrú ni lọ́kàn sókè láti kéde ìhìnrere. Kínni ìdi ti a ó fi máa jẹ́ ki àwọn ènìyàn la nínú ewu kíkọ ìhìnrere kí wọn sì dá ara wọn lẹ̀bi nígbàtí a ti gbà wọ́n là tẹ́lẹ̀ nítorí wọn kò gbọ́ ìhìnrere?
English
Kínni ó ńṣẹlẹ̀ sí àwọn tí kò ní àǹfàní láti gbọ́ nípa Jésù rí? Ṣe Ọlọ́run yóò dá ènìyàn kan tí kò gbọ́ nípa Òun rí lẹ́bi?