settings icon
share icon
Ibeere

Njẹ́ Ọlọ́run ṣì ńfi ìran fún àwọn ènìyàn lónìí? Ṣé ó yẹ kí àwọn onígbàgbọ́ máa retí àwọn ìran gẹ́gẹ́ bíi ìrírí Kristiẹni wọn?

Idahun


Njẹ́ Ọlọ́run lè fi ìran fún àwọn ènìyàn lónìí? Bẹ́ẹ̀ni! Njẹ́ Ọlọ́run ńfi ìran fún àwọn ènìyàn lónìí? Ó ṣeé ṣe. Ṣé o yẹ́ kí á máa retí àwọn ìran kí wọ́n jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ yẹpẹrẹ? Bẹ́ẹ̀kọ́. Bí a ṣe ṣe àkọsílẹ̀ nínú Bíbélì, Ọlọ́run bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà nípasẹ̀ àwọn ìran. Àwọn àpẹẹrẹ ni Jakọbu, Jóséfù, ọkọ Maria; Sọlomọni, Isaiah; Isikiẹli; Daniẹli; Peteru; àti Pọ́ọ̀lù. Wòlíì Joẹli sọ àsọtẹ́lẹ̀ títú àwọn ìran jáde, àpọ́stélì Peteru jẹ́rìsí èyí ní Ìṣe àwọn Apọsteli orí Keji (2). Ó ṣe pàtàkì láti kíyèsí wípé ìyàtọ̀ tí ó wà láàrín ìran àti àlá ni wípé a má ńfún ènìyàn ní ìran nígbàtí o bá wà ní ipò jíjí nígbàtí a ńfún ni ní àlá nígbàtí ènìyàn bá sùn.

Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibi ní ayé, ó jọ wípé Ọlọ́run ńlo àwọn ìran àti àwọn àlá lọ́pọ̀lọpọ̀. Ní àwọn àgbègbè ni ibi tí kò ti si ìwáàsù ìhìnrere tàbí tí èyí tí kéré, àti tí àwọn ènìyàn kò ti ní Bíbélì, Ọlọ́run ńmú ìwáàsù Rẹ̀ lọ bá àwọn ènìyàn tààrà nípasẹ̀ àwọn àlá àti àwọn ìran. Èyí bá àwọn àpẹẹrẹ àwọn ìran nínú Bíbélì mu pátàpátà nípa wípé Ọlọ́run ńlòó láti fi òtítọ́ Rẹ̀ hàn sí àwọn ènìyàn ní àkókò ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn Kristiẹni. Bí Ọlọ́run bá fẹ́ sọ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ráńṣẹ́ fún ẹnìkan, Òun lè lo ohunkóhun tí Òun bá rí—ajíǹrere, ańgẹ́lì, ìran tàbí àlá kan. Ní òtítọ́, Ọlọ́run tún ní agbára láti fún ni ní àwọn ìran ní àwọn agbègbè ní ibi ti ìwáàsù ìhìnrere ti wà tẹ́lẹ̀. Kò sí òdiwọ̀n sí ohun tí Ọlọ́run lè ṣe.

Ní àkókò kannáà, àwa gbọ́dọ̀ kíyèsára nígbàtí o bá nííṣe pẹ̀lú àwọn ìran àti ìtumọ̀ àwọn ìran. Àwa ní láti ni lọ́kàn wípé Bíbélì ti pé, àti wípé ó sọ ohun gbogbo tí a ní láti mọ̀ fún wa. Kọ́kọ́rọ́ òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé bí Ọlọ́run bá fẹ́ fun ni ní ìran kan, yóò bá Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ tí a ti fihàn tẹ́lẹ̀ mu pátápátá. A kò gbọ́dọ̀ fún ìran ní àṣẹ kannáà tàbí èyí tí ó ga ju Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni àṣẹ tí ó ga jùlọ fún ìgbàgbọ́ àti ìṣe Kristiẹni. Bí o bá gbàgbọ́ wípé o ni ìran kan tí o lérò wípé Ọlọ́run fi fún ọ, gbée yẹ̀wò pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa àdúrà kí o sì ríi dájú wípé àlá rẹ wà ní ìbámu pẹ̀lú Ìwé Mímọ́. Nígbà náà gbée yẹ̀wò ohun tí Ọlọ́run yóò fẹ́ kí o ṣe sí ìran rẹ nípa àdúrà (Jakọbu 1:5). Ọlọ́run kò ní fún ẹnìkan ní ìran kan kí Òun wá pa ìtúmọ̀ ìran náà mọ́. Nínú Ìwé Mímọ́, nígbàkuugba tí ẹnìkan bá bi Ọlọ́run léèré fún ìtumọ̀ ìran kan, Ọlọ́run yóò ríi dájú wípé a se àlàyé rẹ̀ fún ẹni náà (Daniẹli 8:15-17).

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Njẹ́ Ọlọ́run ṣì ńfi ìran fún àwọn ènìyàn lónìí? Ṣé ó yẹ kí àwọn onígbàgbọ́ máa retí àwọn ìran gẹ́gẹ́ bíi ìrírí Kristiẹni wọn?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries