Ibeere
Kínni Bíbélì sọ nípa ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn? Báwo ni Kristiẹni ṣe lè borí ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn?
Idahun
Ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn jẹ́ àìlera tí ó tàn káàkiri, tí ó sì ńṣe àkóbá fún ogunlọ́gọ̀ ènìyàn, Kristiẹni àti àwọn tí kìí ṣe Kristiẹni bákan náà. Àwọn tí wọ́n ni ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn lè ní ìrírí ìmọ̀lára ìbànújẹ́ tí ó pọ̀, ìbínú, àìnírètí, àárẹ̀ àti onírúurú àwọn àmìn míìrán. Wọ́n lè ní ìmọ̀lára àìwúlò bẹ́ẹ̀ sì ni kí wọ́n fẹ́ gba ẹ̀mí ara wọn, àwọn nǹkan àti ènìyàn tí wọ́n fẹ́ràn tẹ́lẹ̀ á bẹ̀rẹ̀ sí ní sú wọn. Àwọn àjálù ayé bíi ìpàdánù iṣẹ́, ikú àyànfẹ́, ìkọ̀sílẹ̀ tàbí ìṣòro tí ó jọmọ́ ọpọlọ bíi àṣìlò tàbí àìní-ìgbàgbọ́ nínú ara ẹni ni ó sábà máa ńfa ìbìnújẹ́ ọkàn.
Bíbélì sọ fún wa wípé kí á kún fún ayọ̀ àti ìyìn (Fílíppi 4:4; Romu 15:11), nítorí náà Ọlọ́run fẹ́ kí a gbé ìgbé-ayé tí ó kún fún ayọ̀. Èyí kò rọrùn fún ẹni tí ó ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ kàn, ṣùgbọ́n a lè ṣe àtúnṣe rẹ̀ nípa ẹ̀bùn Ọlọ́run ti àdúrà, ìjíròrò lórí Bíbélì àti ìmúlò rẹ̀, lílo àwọn ẹgbẹ́ ìrànlọ́wọ́, ìpéjọpọ̀ àwọn onígbàgbọ́, ìjẹ́wọ́, ìdáríjì àti ìgbaninímọ̀ràn. A gbọ́dọ̀ mọ̀ọ́ mọ̀ tiraka láti má jẹ́ kí ohun gbogbo máa yípo lára àwa nìkan, ṣùgbọ́n ká jẹ́ kí ìgbìyànjú wa jẹ́ fún ará ìta. A lè tán ìmọ̀lára ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn nígbà tí àwọn tí ó ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá gbé ojú kúrò lára wọn tí wọ́n sì tẹjú mọ́ Kristi àti ẹlòmíràn.
Ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn ti ìlera ara jẹ́ ìṣòro ara tí a gbọ́dọ̀ yẹ̀wò lọ́dọ̀ oníṣègùn. Ó lè má jẹ́ àwọn àjálù ayé ló fàá, bẹ́ẹ̀ sì ni ènìyàn lè má lè dín àwọn àmì rẹ̀ kù nígbà tí ó bá wu ẹni. Lòdì sí ohun tí àwọn míìrán nínú àkójọpọ̀ Kristiẹni gbàgbọ́, ẹ̀ṣẹ̀ kìí sábà fa ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn ti ìlera ara. Àìlera ara tí ó nílò ìtọ́jú pẹ̀lú oògùn tábi/pẹ̀lú ìgbaniníyànjú lè ṣe okùnfà fún ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn nígbà míìrán. Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run lè wo àìsàn kí àìsàn tàbí ìlera sàn. Ṣùgbọ́n, ní ìgbà míìrán, rírí Dókítà fún ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn kò yàtọ̀ sí rírí Dókítà fún ọgbẹ́.
Àwọn nǹkan wà tí àwọn tí ó bá ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn lè ṣe láti dín àníyàn wọn kù. Wọ́n gbọ́dọ̀ ri wípé àwọn dúró nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kódà nígbà tí wọn kò fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ìmọ̀lára lè ṣìwá lọ́nà, ṣùgbọ́n Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dúró láíláí kò sì lè yípadà. A gbọ́dọ̀ pa ìgbàgbọ́ wa mọ́ ṣinṣin nínú Ọlọ́run, kí a sì dìímú ṣinṣin si nígbà tí a bá ńla ìṣòro àtí ìdanwò kọjá. Bíbélì sọ fún wa wípé Ọlọ́run kì yóò jẹ́ kí á rí ìdánwò tí ó ga ju ẹ̀mí wa lọ (1 Kọrinti 10:13). Nítòótọ́, níní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ènìyàn yóò jíyìn fún ìhùwàsí rẹ̀ sí ìpọ́njú, pẹ̀lú gbígba ìrànlọ́wọ́ tí ó nílò láti ọ̀dọ̀ àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́. "Ǹjẹ́ nípasẹ rẹ̀, ẹ jẹ́ kí á máa rúbọ ìyìn sí Ọlọ́run nígbàgbogbo, èyínì ni èso ètè wa, tí ńjẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀" (Heberu 13:15).
English
Kínni Bíbélì sọ nípa ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn? Báwo ni Kristiẹni ṣe lè borí ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn?