Ibeere
Kínni Bíbélì sọ nípa jíjẹ́ ìyá Kristiẹni?
Idahun
Jíjẹ́ ìyá jẹ́ ipa tí ó ṣe pàtàkì tí Olúwa yàn láti fifún ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin. A sọ fún Ìyá Kristiẹni wípé kí ó fẹ́ràn àwọn ọmọ rẹ̀ (Titu 2:4-5), ní ọ̀nà tí kò ní mú ẹ̀gàn bá Olúwa àti Olùgbàlà tí ó ńjẹ́ orúkọ rẹ̀.
Àwọn ọmọ ni ìní Olúwa (Orin Dafidi 127:3-5). Nínú Titu 2:4, ọ̀rọ̀ Gíríkì philoteknos farahàn fún ìyá bí wọ́n ṣe ńfẹ́ràn àwọn ọmọ wọn. Ọ̀rọ̀ náà dúró fún irú "ìfẹ́ abiyamọ" tí ó ṣe pàtàkì. Èrò tí ó jáde láti inú ọ̀rọ̀ náà ní ti ìkẹ́ àwọn ọmọ, àbójútó wọn, kíkó wọn mọ́ra pẹ̀lú ìfẹ́, bíbá àìní wọn pàdé àti bíbá ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ṣọ̀rẹ́ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn tó yàtọ̀ láti ọwọ́ Ọlọ́run wá.
Onírúurú nǹkan ni a pa láṣẹ fún àwọn ìyá Kristiẹni nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run:
Wíwà ní àrọ́wọ́tó¬ — òwúrọ̀, ọ̀sán, àti alẹ́ (Deutarọnọmi 6:6-7)
Nííṣe pẹ̀lú — ìbárakínra, jíjíròrò, ìrònú, àti ríro ìgbé-ayé papọ̀ (Efesu 6:4)
Kíkọ́ni ní — Ìwé Mímọ́ àti àwọn àfojúsùn Bíbélì nípa ayé (Orin Dafidi 78:5-6; Deutarọnọmi 4:10; Efesu 6:4)
Títọ́ni — ríran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti jẹ́ kí àwọn ẹ̀bùn wọ́n dàgbà àti láti mọ okun wọn l'ọ́kùnrin àti l'óbìnrin (Òwe 22:6) àti ẹ̀bùn ẹ̀mí (Romu 12:3-8 àti 1 Kọrinti 12)
Ìbániwí — kíkọ́ ni ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, fífi ìyàtọ̀ hàn nígbà gbogbo, fífẹ́ni, dídúró ṣinṣin (Efesu 6:4; Heberu 12:5-11; Òwe 13:24; 19:18;22:15; 23:13-14; 29:15-17)
Bójútó — pipèsè fun àgbègbè tí ó lè fi àyè fún ìdúrótì ni tí ìbánisọ̀rọ̀ nigbàgbogbo , òmìnira láti kùnà, ìtẹ́wọ́gbà, ìfanimọ́ra, àti ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ (Titu 2:4; 2 Timoteu 1:7; Efesu 4:29-32; 5:1-2; 1 Peteru 3:8-9)
Àwòkọ́ṣe pẹ̀lù Ìwà pípé – gbígbé nípa ohun tí à sọ, jíjẹ́ àwòkọ́ṣe tí ọmọ lè kọ́ nípa "gbígbá mú" èrèdí ìgbé-ayé ìwà bí Ọlọ́run (Deutarọnọmi 4:9, 15, 23; Òwe 10:9; 11:3; Orin Dafidi 37:18, 37).
Bíbéli kò sọ wípé gbogbo obìnrin gbọ́dọ̀ jẹ́ abiyamọ. Ṣùgbọ́n, ó sọ wípé àwọn tí Olúwa bá bùkún láti di ìyá gbọ́dọ̀ ṣe ojúṣe wọn gidigidi. Àwọn ìyá ní ojúṣe tí ó dáyàtọ̀ àti tí ó ṣe pàtàkì nínú ayé àwọn ọmọ. Jíjẹ́ abiyamọ kò kí ńṣe iṣẹ́ tí ó le tàbí nira. Gẹ́gẹ́ bí ìyá ṣe gbé ọmọ nínú oyún, àti gẹ́gẹ́ bí ìyá ṣe ńfún ọmọ ní óńjẹ, tí ó ńtọ́jú ọmọ nígbà èwe, bẹ́ẹ̀ ni, ìyá ńṣe ojúṣe tí ó ńlọ lọ́wọ́lọ́wọ́ nínú ayé àwọn ọmọ wọn, bóyá wọ́n ti bàlágà, jẹ́ àgbàlagbà kékeré tàbí àgbàlagbà tó ti ní ọmọ ti wọn. Nígbàtí ojúṣe ìyá ńyí padà àti wípé ó ńpọ̀si, ìfẹ́, ìkẹ́, ìgẹ̀ àti àdúrótí tí ìyá fún ni, kò gbọ́dọ̀ dáwọ́ dúró.
English
Kínni Bíbélì sọ nípa jíjẹ́ ìyá Kristiẹni?