settings icon
share icon
Ibeere

Ṣé ẹ̀mí èṣù lè gbé Kristiẹni wọ̀? Ṣé Kristiẹni lè kún fún ẹ̀mí èṣù?

Idahun


Nígbàtí Bíbélì kò ṣ'àlàyé bóyà ẹ̀mí èṣù lè gbé Kristiẹni wọ̀, àwọn òtítọ́ tí ó farapẹ́ Bíbélì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ dájúdájú wípé ẹ̀mí èṣù kò lè gbé àwọn Kristiẹni wọ̀. Ìyàtọ̀ gedegbe ló wà láàrin kí ẹ̀mí èṣù gbé ènìyàn wọ̀ àti kí ẹ̀mí èṣù máa ní ènìyàn lára tàbí ní ipa lórí ènìyàn. Kí ẹ̀mí èṣù gbé ènìyàn wọ̀ niíṣe pẹ̀lú kí ẹ̀mí èṣù máa darí tàbí ṣe àkóso èrò tàbí ìṣe ènìyàn l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́ (Matteu 17:14-18; Luku 4:33-35; 8:27-33). Kí ẹ̀mí èṣù máa ni ènìyàn lára tàbi ní ipa lórí ènìyàn ní nínú kí ẹ̀mí èṣù máa gbógun ti ènìyàn ní ti ẹ̀mí àti/tàbi gbígbaninímọ̀nràn láti hùwà ẹ̀ṣẹ̀. Kíyèsi wípé láti inú àwọn ìwé Májẹ̀mu Titun tí ó sọ nípa ìja ẹ̀mí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé, kò sí ibi tí a ti sọ wípé kí á lé ẹ̀mí èṣù jáde lára ònígbàgbọ́ (Efesu 6:10-18). A sọ fún àwọn onígbàgbọ́ wípé kí wọn kọjú ìjà sí èsu (Jakọbu 4:7; 1 Peteru 5:8-9), kìí ṣe wípé kí á lé jáde.

Ẹ̀mí mìmọ́ ńgbé inú àwọn Kristiẹni (Romu 8:9-11; 1 Kọrinti 3:16; 6:19). Dájudájú Ẹ̀mí Mímọ́ kò ní gbà ẹ̀mí èṣù láàyè nínú ẹni tí Òun bá ńgbé. Kò ṣeé rò wípé Ọlọ́run yóò gba láàyè ọ̀kan lára àwọn ọmọ Rẹ̀, tí Òun ti fi ẹ̀jẹ̀ Kristi ràpadà (1 Peteru 1: 18-19), tí a ti sọ di ẹ̀dá titun (2 Kọrinti 5:17), láti di ẹni tí ẹ̀mí èṣù yóò gbé wọ̀ tàbí ṣe ìṣàkóso. Bẹ́ẹ̀ni, gẹ́gẹ́ bíi ònígbàgbọ́, à ńkọjú ìjà sí sàtánì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ṣùgbọ́n kìí ṣe nínú wa. Àpọ́stélì Johannu wípé "Ẹ̀yin ọmọde, ti Ọlọrun nìyín, ẹ ti ṣẹgun ẹ̀mí alátakò Kristi nítorí pé ẹni tí ó wà ninu yín tóbi ju ẹni tí ó wà ninu ayé lọ" (1 Johannu 4:4). Tani Ẹni tí ó wà nínú wa? Ẹ̀mí Mímọ́ náà ni. Tani ẹni tí ó wà nínú ayé? Sàtánì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Nítorínáà, ònígbàgbọ́ tí ṣẹ́gun ayé tí ó kún fún àwọn ẹ̀mí èṣù, kò bá bíbélì mu láti sọ wípé ẹ̀mí èṣù gbé ònígbàgbọ́ wọ̀.

Pẹ̀lú ẹ̀rí tí ó dájú gan-an nínú bíbélì wípé ẹ̀mí èṣù kò lè gbé Kristiẹni wọ̀, àwọn Olùkọ́ Bíbélì kan lo ọ̀rọ̀ bíi "lábẹ́ ìṣàkóso ẹ̀mí èṣù" láti ṣàlàyé wípé ẹ̀mí èṣù le ṣàkóso lórí Kristiẹni. Àwọn míìrán jiyàn wípé, ẹ̀mí èṣù kò le gbé inú Kristiẹni ṣùgbọ́n ó le ṣàkóso lórí Kristiẹni. Bí a bá wòó fínnífínní, àpèjúwe ṣísàkóso ẹ̀mí èṣù àti gbígbé ni wọ̀ ẹ̀mí èṣù kò yàtọ̀. Nítorínáà, àbájáde kannáà ló jásí. Yíyí ọ̀rọ̀ yí padà kò yí ìtítọ́ náà padà wípé, ẹ̀mí èṣù kò lè gbé inú Kristiẹni tàbí ṣàkóso ayé Kristiẹni. Ipa àti ìṣàkóso ẹ̀mí èṣù jẹ́ ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ fún Kristiẹni,láì ṣe iyèméjì, ṣùgbọ́n, kò bá bíbélì mu ní kúkúrú láti wípé ẹ̀mí èṣù le gbé inú ayé Kristiẹni tàbí ṣàkóso rẹ̀.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn èròǹgbà tí ó wà lẹ́yìn ẹ̀kọ́ ìṣàkóso ẹ̀mí èṣù ni ìrírí tí àwọn kan ní nígbà tí wọ́n rí àwọn Kristiẹni tí wọ́n ṣe bíi ẹnití ẹ̀mí èṣù ńdarí "lóòtọ́". Ó ṣe pàtàkì pé kí á má jẹ̀ kí ìrírí tí ara ẹni láti kóbá bí a ti ṣe ńtúmọ̀ Ìwé Mímọ́. Dípò bẹ́è, àwa gbọ́dọ̀ yiri ìrírí tí a ní nípasẹ̀ òtítọ́ Ìwé Mímọ́ (2 Timoteu 3:16-17). Rírí ẹnìkan tí a rò wípé ó jẹ́ Kristiẹni tí ó ńwùwà bíi ẹnití ẹ̀mí èṣù ńdarí má ńjẹ́ kí àwọn ènìyàn kẹ́gàn jíjẹ́ ojúlówó ìgbàgbọ́ ẹni náà. Èyí kò gbọdọ̀ jẹ́ kí á sọ àfojúsùn wa nù lóríi bóyá ẹ̀mí èṣù gbé Kristiẹni wọ̀ tàbí wà lábẹ́ ìṣàkóso ẹ̀mí èṣù. Bóyà ènìyàn náà jẹ́ Kristiẹni tóòtọ́ ṣùgbọ́n ẹ̀mí èṣù ńgbé inú ayé rẹ̀ tàbí ni ayé rẹ̀ lára tí ó sì ní ìṣòro tí ó ńda ọkàn rẹ̀ láàmú. Lẹ́ẹ̀kan si, àwọn ìrírí wa gbọ́dọ̀ bá ìdanwò inú Ìwé Mímọ́ mu, kìí ṣe ní ọ̀nà kejì.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Ṣé ẹ̀mí èṣù lè gbé Kristiẹni wọ̀? Ṣé Kristiẹni lè kún fún ẹ̀mí èṣù?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries