settings icon
share icon
Ibeere

Kínni ìdí tí lílọ sí ilé-ìjọ́sìn fi ṣe pàtàkì?

Idahun


Bíbélì sọ fún wa wípé a nílò láti lọ sí ilé-ìjọ́sìn kí á le sin Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ míìrán kí á sì kọ́ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ fún ìdàgbà ẹ̀mí wa. Ìjọ àkọ́kọ́ "dúró sinsin nínú ẹ̀kọ́ àwọn apọsteli, àti ní ìdàpọ̀, ní bíbu àkàrà àti nínú àdúrà" (Iṣe Apọsteli 2:42). A gbọ́dọ̀ tẹ̀lé àpẹẹrẹ ìdúró sinsin náà—àti sí àwọn ohun kaǹnáà. Nígbà kan, wọn kò ní ilé kankan tí wọ́n yàn fún ìjọ́sìn, ṣùgbọ́n "wọ́n sì ńfi ọkàn kan dúró li ojoójúmọ́ nínú tẹ́mpìlì àti ni bibu àkàrà ní ilé, wọ́n ńfi inú dídùn àti ọkàn kan jẹ oúnjẹ wọn" (Iṣe àwọn Apọsteli 2:46). Ibikíbi tí ìpàdé náà bá ti wáyé, àwọn onígbàgbọ́ sì ńmú kí ìjọ́sìn pẹ̀lú àwọn ònígbàgbọ́ yòókù àtí ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ̀run gbèèrú síi.

Lílọ sí ilé-ìjọsìn kìí ṣe "àbá kan tí ó dára" nìkan; ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run fún àwọn onígbàgbọ́. Heberu 10:25 sọ wípé a kò gbọdọ̀ "kọ ìpéjọpọ̀ ara wa silẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn ẹlòmíràn; ṣùgbọ́n kí á má a gba ara ẹni níyànjú-pẹ̀lúpẹ̀lú bí ẹ̀yin ti rí pé ọjọ́ nì súnmọ́ etílé." Kódà ní ìjọ àkọ́kọ́, àwọn kan ńṣubú sínú ìwà búburú nípa kíkọ́ ìpéjọpọ̀ ará sílẹ̀. Ònkọ̀we Heberu sọ wípé kìí ṣe ọ̀nà t'óyẹ ká gbà nìyẹn. A nílò ìyànjú tí lílọ sí ilé-ìjọsìn ńgbà. Àti wípé sísúnmọ́ ìgbà ìkẹyìn gbọ́dọ̀ mú kí á fi ara jìn sí lílọ sí ilé-ìjọsìn.

Ilé-ìjọsìn jẹ́ ibi tí àwọn onígbàgbọ́ ti le fẹ́ràn ara wọn (1 Johannu 4:12), gba ara ẹni níyànjú (Heberu 3:13), "ńru" ara ẹni sí ìfẹ́ àti ìsẹ rere (Heberu 10:24), sin ara ẹni (Gàlátíà 5:13), tọ́ ara-ẹni (Romu 15:14), bọ̀wọ̀ fún ara-ẹni (Romu 12:10), àti ṣe dáradára kí á sì ní àánú sí ara ẹni (Efesu 4:32).

Nígbàtí ènìyàn bá gbẹ́kẹ̀lé Jésù Kristi fún ìgbàlà, ó ti di ara Kristi (1 Kọrinti 12:27). Kí ara ìjọ tó le ṣiṣẹ́ dáradára; gbogbo "ẹ̀yà ara" rẹ̀ nílò láti wà kí ó sì ma ṣiṣẹ́ (1 Kọrinti 12:14-20). Kò tó láti lọ sí ìjọ kan lásán; a gbọ́dọ̀ kópa nínú iṣẹ́ ìráńsẹ́ kan tàbí òmíràn, kí á sì máa lo àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí tí Ọlọ́run ti fifún wa (Efesu 4:11-13). Onígbàgbọ́ kan kò le dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdàgbà ẹ̀mí láìní ìṣàn náà fún àwọn ẹ̀bùn rẹ̀, àti wípé gbogbo wa ni o nílò ìrànlọ́wọ́ àti ìgbaniníyànjú àwọn onígbàgbọ́ míìrán (1 Kọrinti 12:21-26).

Fún ìdí èyí àti òmíràn, lílọ sí ilé-ìjọ́sìn, kíkópa, àti ìdàpọ̀ gbọ́dọ̀ ṣe deede nínú ìgbé-ayé onígbàgbọ́. Lílọ sí ilé-ìjọ́sìn l'ọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ kò "mú" ọpọlọ dání fún àwọn onígbàgbọ́, ṣùgbọ́n ẹnití ó bá jẹ́ ti Kristi gbọ́dọ̀ n'ífẹ̀ẹ́ sí sísin Ọlọ́run, gba Ọ̀rọ Rẹ̀, àti jọ́sìn pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ míìrán.

Jésù jẹ́ Igun-ilé Ìjọ (1 Peteru 2:6), àti àwa pẹ̀lú "bíi òkúta ààyè . . . tí a kọ́ ní ilé ẹ̀mí, àlúfà mímọ́, láti máa rú ẹbọ ẹ̀mí, tí íṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípa Jésù Kristi" (1 Peteru 2:5). Gẹ́gẹ́ bí èrònjà ìkọ́lé "Ilé ẹ̀mí" Ọlọ́run, a ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ara wa, ìsopọ̀ náà sí hàn kedere ní gbogbo ìgbà tí àwọn ìjọ "bá lọ sí ilé-ìjọ́sìn."

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni ìdí tí lílọ sí ilé-ìjọ́sìn fi ṣe pàtàkì?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries