Ibeere
Báwo ni mo ṣe lè mọ̀ bí mo bá wà nínú ìfẹ́?
Idahun
Ìfẹ́ jẹ́ ìmọ̀lára kan tí o lágbára gan-an. Ó máa ńmú ìwúrí bá àwọn ìgbé-ayé wa. Àwa ńṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpinnu pàtàkì tí ó dá lórí ìmọ̀lára yìí, àti pàápàá à ńṣe ìgbéyàwó nítorí a rò wípé a ti wà "nínú ìfẹ́." Èyí lè jẹ́ ìdí tí bíi ìdajì nínú gbogbo àwọn ìgbéyàwó àkọ́kọ́ ṣe ńparí sí ìkọ̀sílẹ̀. Bíbélí náà ńkọ́ wa wípé ìfẹ́ kò jẹ́ ìmọ̀lára tí ó máa ńwá tàbì lọ, ṣùgbọ́n ìpinnu kan. A kò gbọ́dọ̀ ní ìfẹ́ àwọn tí o fẹ́ràn wa nìkan; a tún gbọ́dọ̀ fẹ́ràn àwọn tí ó kórira wa, ní ọ̀nà kan náà tí Kristi fi ńfẹ́ ẹni tí a kò lè fẹ́ràn (Luku 6:35). "Ìfẹ́ a máa mú sùúrù, a sì máa ṣeun. Kìí ṣe ìlara; ìfẹ́ kìí sọ̀rọ̀ ìgbé-raga, kìí fẹ̀. Kìí hùwà àìtọ́, kìí wa ohun ti ara rẹ, a kìí múu bínú, bẹ́ẹ̀ li kìí gbero ohun búburú. Ìfẹ́ kìí yọ̀ sí àìṣòdodo, ṣùgbọ́n a máa yọ̀ nínú òtítọ́. Òhun máa ńdáàbòbò ní ìgbà gbogbo, a máa gba ohun gbogbo gbọ̀, a máa retí ohun gbogbo, máa farada ohun gbogbo"(1 Kọrinti 13:4-7).
Ó lè rọ̀rùn gan-an láti "yó ìfẹ́" pẹ̀lú ẹnìkan, ṣùgbọ́n àwọn ìbéèrè kan ńbẹ láti bèèrè ṣáájú kí á tó pinnu bí ohun tí a ńní ìmọ̀lára rẹ̀ bá jẹ́ ìfẹ́ òtítọ́. Àkọ́kọ́, ǹjẹ́ ẹni yìí jẹ́ Kristiẹni, èyítí ó ńtúmọ̀ sí wípé ǹjẹ́ ó ti fi ayé rẹ̀ fún Kristi? Ǹjẹ́ òun ńgbẹ́kẹ̀lé Kristi nìkanṣoṣo fún ìgbàlà? Bákannáà, bí o bá ńfiyèsì láti fi ọkàn rẹ àti àwọn ìmọ̀lára rẹ fún ẹnìkan, o gbọ́dọ̀ bi ara rẹ ní ìbéèré bí o bá ńfínú fẹ́dọ̀ rẹ láti gbé ẹni náà lékè gbogbo àwọn ènìyàn yóókù àti láti gbé ìbáṣepọ̀ rẹ ṣìkejì sí Ọlọ́run nìkan ṣoṣo. Bíbélì náà sọ fún wa wípé nígbàtí àwọn ẹni méjì bá ṣe ìgbéyàwó, wọn di ara kan (Jẹnẹsisi 2:24; Matteu 19:5).
Ohun míìrán láti fiyèsí ni bóyá ẹni náà tí a fẹ́ràn jẹ́ olùkópa fún jí jẹ́ olùbákẹ́gbẹ́pọ̀ tàbí bẹ́ẹ̀kọ́. Ǹjẹ́ òun ti fi Ọlọ́run ṣe àkọ́kọ́ tẹ́lẹ̀ àti àkọ́kọ́ jùlọ nínú ayé rẹ̀? Ǹjẹ́ òun lè fi àkókò àti agbára rẹ̀ láti kọ ìbáṣepọ̀ wọ inú ìgbéyàwó kan èyí tí yòó ní ìparí ọjọ́ ayé kan? Kò sí igi òdiwọ̀n kan láti mọ̀ ìgbà tí a ba ti yó ìfẹ́ pẹ̀lú ẹnìkan, ṣùgbọ̀n o ṣe pàtàkì láti ṣe ìdámọyàtọ̀ bóyá à ntẹ̀lé àwọn ìmọ̀lára wa tàbí a ńtẹ̀lé ìfẹ́ ti Ọlọ́run fún ìgbé-ayé wa. Ìfẹ́ òtító jẹ́ ìpinnu, kìí kàn ṣe ìmọ̀lára. Ìfẹ́ òtítọ́ tí ó bá Bíbélì mu jẹ́ fí fẹ́ràn ẹnìkan nígbàgbogbo, kìí kàn ṣe nígbàtí o bá ńfẹ́ "yó ìfẹ́."
English
Báwo ni mo ṣe lè mọ̀ bí mo bá wà nínú ìfẹ́?