settings icon
share icon
Ibeere

Kínni Bíbélì sọ nípa jíjẹ́ òbí rere?

Idahun


Títọ́jú ọmọ lè jẹ́ òwò tí ó le, tí ó sì ní àwọn ìdojúkọ, ṣùgbọ́n nígbà kan náà, ó lè jẹ́ nǹkan tí ó lérè nínú tí ó sì lè fún ni láyọ̀ jù, tí ènìyàn lè ṣe. Bíbélì ni ọ̀pọ̀ láti sọ nípa ọ̀nà tí a lè fi ṣe àṣeyọrí nínú kíkọ́ àwọn ọmọ wa láti di ènìyàn Ọlọ́run l'ọ́kùnrin àti l'óbìnrin. Ohun àkọ́kọ́ tí a gbọ́dọ̀ ṣe ni láti kọ́ wọn ní òtítọ́ ti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Pẹ̀lú fífẹ́ Ọlọ́run àti jíjẹ́ àwòkọ́ṣe ìwà bíi ti Ọlọ́run nípa fífi araẹnijì fún àṣẹ Rẹ̀, a nílò láti gbọ́ràn sí àṣẹ tí ó wà nínú ìwé Deutarọnọmi 6:7-9 nípa kíkọ́ àwọn ọmọ wa láti ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Àyọkà yìí ṣe àtẹnumọ́ lóri àbùdá tí à ńlò lọ́wọ́ lórí irúfẹ́ àṣẹ bẹ́ẹ̀. Ó gbọ́dọ̀ di ṣíṣe ìgbà gbogbo—ní ilé, l'ójú ọ̀nà, ní alẹ́ àti l'ówúrọ̀. Òtítọ́ Bíbélì gbọ́dọ̀ jẹ́ ìpìlẹ̀ fún ilé wa. Nípa títẹ̀lẹ́ àwọn ìlànà òfin yìí, àwa ńkọ́ àwọn ọmọ wípé sínsin Ọlọ́run gbọ́dọ̀ jẹ́ ìgbà gbogbo, kìí ṣe fún òwúrọ̀ ọjọ́ ìsinmi tàbi àdúrà alẹ́ nìkan.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé, àwọn ọmọ wa ń kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa kíkọ́ ni tààrà, wọ́n ńkọ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ bí wọ́n ṣe ńwò wá. Nítorí èyí, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra nínú ohun gbogbo tí a bá ńṣe. A gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ àwọn ojúṣe tí Ọlọ́run fún wa. Àwọn ọkọ àti ìyàwó gbọ́dọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn, kí wọ́n sì máa tẹríba fún ara wọn (Efesu 5:21). Nígbà kan náà, Ọlọ́run gbé olórí kalẹ̀ kí ètò lè wà. "Ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé, Kristi ni olórí olúkúlúkù ọkùnrin, orí obìnrin sì ni ọkọ rẹ̀; àti orí Krístíì sì ni Ọlọ́run" (1 Kọrinti 11:3). Àwa mọ̀ wípé Kristi kìí ṣe gbàntú ẹ̀yọ̀ sí Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìyàwó kò kéré sí ọkọ. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run mọ̀ wípé láì sí ìtẹríba fún olórí, kò lè sí ètò. Ojúṣe ọkọ gẹ́gẹ́ bí olórí ilé ni láti fẹ́ràn ìyàwó rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe fẹ́ràn ara rẹ̀, ní ìfẹ́ àìlẹ́tàn bí Kristi ṣe fẹ́ràn ìjọ (Efesu 5:25-29).

Ní ìdáhùn sí ìdarí ìfẹ́ yíì, kò lera fún ìyàwó láti tẹríba fún àṣe ọkọ rẹ̀ (Efesu 5:24; Kolosse 3:18). Ojúṣe àkọ́kọ́ rẹ̀ ni láti ní ìfẹ́ àti tẹríba fún ọkọ rẹ̀, gbé nínú ọgbọ́n àti ìwà mímọ́, kí wọ́n sì ṣe ìtọ́jú ilé (Titu 2:4-5). Àbùdá obìnrin ni láti mọ ìtọ́jú ṣe ju ọkùnrin lọ, nítorí wípé a dá wọn láti jẹ́ olùtọ́jú fún àwọn ọmọ wọn.

Ìbáwí àti ìtọ́ni jẹ́ ipa tí ó ṣe pàtàkì nínú títọ́jú ọmọ. Òwe 13:24 sọ wípé, "ẹnití ó bá fa ọwọ́ pàsán sẹ́yìn, ó kóríra ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹnití ó fẹ́ẹ á máa tètè nàá." Àwọn ọmọ tí ó dàgbà ní ilé tí kò sí ìbáwí máa ńrò wípé wọn kò nílò àwọn, wípé àwọn kò wúlò. Wọn kò ní ìtọ́ni àti ìkóra-ẹniní ìjánu, bí wọ́n sì ṣe ńdàgbà, wọn á máa ṣe àìgbọràn àti wípé wọ́n a máa bọ̀wọ̀ díẹ̀ tàbí kí wọ́n tilẹ̀ má bọ̀wọ̀ rára fún àṣẹ kankan, pẹ̀lú àṣẹ ti Ọlọ́run gan. "Na ọmọ rẹ nígbàtí ìrètí wà; má sì ṣe gbé ọkàn rẹ lé àti pá a"( Òwe 19:18). Nígbà kan náà, ìbáwí gbọ́dọ̀ wà nínú ìfẹ́, bíbẹ́ẹ̀ kọ́, àwọn ọmọ lè ní ìkorò, ìrẹ̀wẹ̀sì àti àìgbọràn tí wọ́n bá dàgbà (Kolosse 3:21). Ọlọ́run mọ̀ wípé ìbáwí korò nígbà tí ó bá ńṣẹlẹ̀ (Heberu 12:11), ṣùgbọ́n bí ìkìlọ̀ nínú ìfẹ́ bá tẹ̀le, yóò ṣe ọmọ náà ní àǹfàní púpọ̀. "Àti ẹ̀yin Bàbá, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú: ṣùgbọ́n ẹ máa tọ́ wọn nínú ẹ̀kọ́ àti ìkìlọ̀ Olúwa." (Efesu 6:4).

Ó ṣe pàtàkì láti jẹ́ kí àwọn ọmọ lọ́wọ́sí ìjọ ti ìdílé àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ nígbàtí wọ́n bá sì kéré. Kí wọ́n máa lọ sí ìjọ tí ó gbàgbọ́ nínú Bíbélì (Heberu 10:25), gbà wọ́n láàyè láti rí kíkọ́ ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ náà, kí a sì máa kọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀ pẹ̀lú wọn. Jíròrò nípa ayé tí ó yí wọn ká pẹ̀lù wọn, kí o sì kọ́ wọn nípa ògo Ọlọ́run yípo ọjọ́. Èyí mú wa lọ sí ìwé Òwe 22:6, " Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yíó tọ̀, nígbàtì ó sì dàgbà tán , kì yó ò kúrò nínú rẹ̀" (Òwe 22:6). Jíjẹ́ òbí rere ní í ṣe pẹ̀lú kíkọ́ àwọn ọmọ tí yóò tẹ̀lé àpẹẹrẹ rẹ nínú ìgbọràn àti sínsin Olúwa.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni Bíbélì sọ nípa jíjẹ́ òbí rere?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries