Ibeere
Báwo ni mo ṣe lè dá olùkọ́ èké/wòlíì èké mọ̀?
Idahun
Jésù kìlọ̀ fún wa wípé "àwọn Krísti èké àti àwọn wòlíì èké" yóò wá tí wọ́n yóò gbìyànjú láti tan àwọn ènìyàn jẹ kódà àyànfẹ́ Ọlọ́run (Matteu 24:23-27; tún wo 2 Peteru 3:3 àti Juda 17-18). Ọ̀nà tí ó dára jùlọ láti dáàbòbò ara rẹ lòdì sí irọ́ àti àwọn ọlùkọ́ èké ní láti mọ òtítọ́ náà. Láti dá ayédèrú mọ̀, kọ́ ẹ̀kọ́ ohun tí ó jẹ́ gidi. Onìgbàgbọ́ yóò wù tí "ó ńpín ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí ó ti yẹ" (2 Timotiu 2:15) àti ẹni tí ó ńṣe àkíyèsi ẹ̀kọ́ kíkọ́ ti Bíbélì ni yóò lè dá ẹ̀kọ́ èké mọ̀. Fún àpẹẹ́rẹ, onígbàgbọ́ tí ó ti ka àwọn iṣẹ́ ti Baba, Ọmọ, àti Ẹ̀mi Mímọ́ nínú Matteu 3:16-17 yóò ṣe ìbéèrè sí ẹ̀kọ́ kẹ́ kọ̀ tí ó kọ Mẹ́talọ̀kan. Nítorí náà, ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ní láti kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì àti ṣe ìdájọ́ gbogbo ẹ̀kọ́ nípasẹ̀ ohun tí Ìwé Mímọ́ ńsọ.
Jésù wípé "a ó dà á igi kan mọ̀ nípa èso rẹ̀" (Matteu 12:33). Nígbà tí a bá ńwá "èso" àwọn ìdánwò mẹ́ta pàtó nìyí tí a ó ṣe sí olùkọ́ yóò wù láti lè mọ wípé ẹ̀kọ́ rẹ̀ l'ọ́kùnrin tàbì l'óbìnrin pé lẹ́kùnrẹ́rẹ́:
1) Kínni olùkọ́ yìí sọ nípa Jésù? Nínú Matteu 16:15-16, Jésù ńbèrè, "Tani ẹ̀yín ń fi mí pè?" Peteru dáhùn, "Krístì, Ọmọ Ọlọ́run alààyè ní ìwọ́ íṣe," àti fún ìdáhùn èyí a pe Peteru ni "alábùkúnfún." Nínú Johannu kejì ẹsẹ̀ 9, a kà, "Olúkùlùkù ẹni tí ó bá ń rú òfin tí kò sí dúró nínú ẹ̀kọ́ Krístì, kò gba Ọlọ́run; ẹni tí ó bá dúró nínú ẹ̀kọ́, òun ni ó gba àti Baba àti Ọmọ." Ní èdè míìrán, Jésù Kristi àti iṣẹ́ ìràpadà Rẹ̀ jẹ́ èyí tí ó ṣe pàtàkì jùlọ; ẹ kíyèsára fún ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ wípé Jésù jẹ́ ìkannáà pẹ̀lú Ọlọ́run, tí ó sì ńbu ẹnu àtẹ́ lu ikú irúbọ ti Jésù tàbí tí ó kọ jíjẹ́ ènìyàn ti Jésù. Johanu Kìnní 2:22 ńwípé, "Tani èké? Bíkòṣe ẹni tí ó bá sẹ́ pé Jésù kìí ṣe Kristi náà. Eléyìí ni aṣòdì-krístì—ẹni tí ó bá sẹ́ Baba àti Ọmọ."
2) Ǹjẹ́ olùkọ́ yìí ńwàásù ìhìnrere náà? Ìhìnrere ni ó túmọ̀ sí àwọn ìròyìn rere nípa ikú Jésù, ìsìnku, àti àjínde rẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn Ìwé Mímọ́ (1 Kọrinti 15: 1-4). Bí ó ṣe dùn láti gbọ́ wọ́n tó, àwọn gbólóhùn, "Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ," Ọlọ̀run fẹ́ kí a bọ́ àwọn tí ebí ń pa," àti "Ọlọ́run ń fẹ́ kí o lọ́rọ̀" kìí ṣe ìfiránṣẹ́ pípé nípa ìhìnrere. Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti kìlọ̀ nínú Galatia 1:7, "Bí ó tilẹ̀ ṣe pé, àwọn kan wà tí wọ́n ń yọ yín lẹ́nu tí wọn sì ń fẹ́ yí ìhìnrere Krístì padà." Kò sì ẹnikẹ́ni, kódà oníwàásù ńlá, tí ó ní ẹ̀tọ́ láti ṣe àyípadà ọ̀rọ̀ náà ti Ọlọ́run fún wa. "Bí ẹnikẹ́ni bá ń wàásù fún yín ìhìnrere yàtọ̀ sí ohun tí ẹ gbà, jẹ́ kí ó di ẹni ìdálẹ́bi tìtí láí!" (Galatia 1:9).
3) Ǹjẹ́ olùkọ́ yi ńṣe àfihàn àbùdá àmúyẹ tí ó fi ògo fún Olúwa? Ní sí sọ̀rọ̀ nípa àwọn olùkọ́ èké, Juda 11 wípé, "Wọ́n ti tọ ọ̀na ti Káìnì; wọ́n tí du èrè sínú èké ti Bálámù; a ti pa wọ́n run nínú ìṣọ̀tẹ̀ ti Kórà." Ní èdè míìrán, olùkọ́ èké ni a lè dá mọ̀ nípa ìgbéraga rẹ̀ (ìkọ̀sílẹ̀ ètò Ọlọ́run ti Káìnì), ojúkòkúrò (ìsọtẹ́lẹ̀ ti Bálámù fún owó), àti ìṣọ̀tẹ̀, (ìgbé ara ẹni sókè tí Kórà lórí Mósè). Jésù wípé kí á ṣọ́ra fún irú àwọn wọ̀nyìí àti wípé a ó dá wọn mọ̀ nípa àwọn èso wọn (Matteu 7:15-20).
Fún ẹ̀kọ́ síwájú si, ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn ìwé wọ̀nyìí ti Bíbélì tí a kọ sílẹ̀ ní pàtó láti gbógun ti ẹ̀kọ́ èké nínú ìjọ: Galatia, 2 Peteru, 1 Johannu, 2 Johannu, àti Juda. Ó máa ńṣòro láti tọ́kasí olúkọ́ èké/wòlìí èké. Sátánì a máa fi agọ̀ bojú bíi ańgẹ́lì ti ìmọ́lẹ̀ (2 Kọrinti 11:14), tí àwọn ìránṣẹ rẹ̀ á máa farahàn bíi ìránṣẹ́ òdodo (2 Kọrinti 11:15). Nípa wíwà ní ìfarakínra pẹ̀lú òtítọ́ nìkan ṣoṣo ní a lè fi dá ayédèrú kan mọ̀.
English
Báwo ni mo ṣe lè dá olùkọ́ èké/wòlíì èké mọ̀?