Ibeere
Kínni àwọn òbi Kristẹini gbọ́dọ̀ ṣe tí wọ́n bá ni ọmọkùnrin onínàákúnà (tàbí ọmọbìnrin)?
Idahun
Onírúurú ìláná ni ó wà nínú ìtàn ọmọkùnrin onínàákúnà (Luku 15:11-32) tí àwọn òbí onígbàgbọ́ lè lò láti hùwàsí àti kojú àwọn ọmọ tí ó tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ sí ọ̀nà tí òbí kọ́ wọn. Òbí nílò láti rántí wípé níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọmọ bá ti dé ipò àgbà, wọn kò sí lábẹ́ àṣẹ àwọn òbí mọ́.
Nínú ìtàn ọmọkùnrin onínàákúnà, ọmọkùnrin tí ó kéré jù gba ogún-ìni tí ó kàn án, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n lọ sí ilẹ̀ òkèrè, ó sì fi ṣòfò. Ní ipò ọmọ tí kò tíì di àtúnbí, èyí jẹ́ ṣíṣe ohun tí ó bá kan wá ní ti ara. Ní ipò ti ọmọ tí ó ti ṣe ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ nínú Kristi ní ìgbà kan, àwa yóò pe ọmọ náà ní "onínàákúnà". Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà ni wípé " ẹni tí ó ná ohun àlùmọ́nì rẹ̀ ní ìná àpà", àpèjúwe tí ó dára nípa ọmọ tí ó kúrò ní ilé, tí ó sì ná ogún-ìní ẹ̀mí rẹ̀ tí àwọn òbí rẹ̀ ti fi pamọ́ fun ní ìnákúná. Àwọn ọdún àtọ́jútó, ìkọ́ni, ìfẹ́ àti ìkẹ́ di ohun ìgbàgbé bí ọmọ yìí ṣe ṣe ọ̀tẹ̀ lòdì sí Ọlọ́run. Ní akọ́kọ́, fún gbogbo ìṣọ̀tẹ̀ lòdì sí Ọlọ́run, tí ó farahàn nínú ìṣọ̀tẹ̀ lòdì sí òbí àtí àwọn aláṣẹ.
Kíyèsi wípé, nínú ìtàn yìí bàbá kò dí ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ láti má lọ. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò sáré tẹ̀lé ọmọ rẹ̀ láti gbìyànjú dáàbòbòó. Dípò bẹ́ẹ̀é, òbí yìí fọkàn kan dúró nílé tí ó sì ńgbàdúrà, nígbàtí "ojú rẹ̀ bá wálẹ̀", tí ó sì yípo tí ó padà, òbí náà ńretí rẹ̀, ó ńwo ọ̀nà, tí ó sì sáré láti ki ọmọ náà nígbàtí ó "sì wà ní òkèrè".
Nígbàtí àwọn ọmọ wá bá yapa kúrò fúnra wọn— tí wọ́n lérò wípé àwọn ti wà lọ́jọ́ orí tó bá òfin mu láti ṣe bẹ́ẹ̀— tí wọ́n sì ṣe àwọn ìpinnu tí a mọ̀ wípé àtubọ̀tán rẹ̀ yóò léwu, àwọn òbí gbọ́dọ̀ yọ̀nda, kí wọ́n sì gbà wọ́n láyè láti lọ. Òbí náà kò sáré tẹ̀lée, òbí náà kò ṣe ìdènà sí àtubọ̀tán tí ó ńbọ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, òbí náà dúró nílé, òbí náà fọkàn kan ńgbàdúrà, tí ó sì ńdúró wo àmì ìrònúpìwàdà àtí ìyípadà ọ̀nà. Títí èyí yóò fi ṣẹlẹ̀, àwọn òbí gbọ́dọ̀ pa ìmọ̀ràn wọn mọ́, kí wọ́n má fọwọ́ sí ìṣọ̀tẹ̀ lòdì sí wọn, kí wọ́n má sì tojú bọ ọ̀ràn wọn (1 Peteru 4:15).
Níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọmọ bá ti wà lọ́jọ́ orí tí ó bá òfin mu láti dé ipò àgbà, wọn wà lábẹ́ àṣẹ Ọlọ́run nìkan àti àwọn aláṣẹ tí a ti yàn láti ṣe ìjọba (Romu 13:1-7). Gẹ́gẹ́ bí òbí, a lè ran àwọn ọmọ onínàákúnà lọ́wọ́ pẹ̀lú ìfẹ́ àti àdúrà, kí á sì ṣetán láti wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn lọ́gán tí wọ́n bá gbèrò láti padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Lọ́pọ̀ ìgbà Ọlọ́run a máa lo òṣí tí a fọwọ́ fà sórí ara wa láti mú wa wà sí ọgbọ́n, ó wá kù sí ọwọ́ oníkálùkù láti dáhùn lọ́nà tí ó tọ́. Gẹ́gẹ́ bí òbí, a kò lè gba àwọn ọmọ wa là—Ọlọ́run nìkan ló lè ṣe bẹ́ẹ̀. Títí tí àkókò náà yóò fi dé, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra, kí á sì máa gbàdúrà, kí á sì fi ọ̀ràn náà lé Ọlọ́run lọ́wọ́. Èyí lè nira láti ṣe, ṣùgbọ́n tí a bá ṣeé gẹ́gẹ́ bí ìlànà Bíbélì, yóò mú àlàáfíà wá sí ọkàn àti àyà wa. A kò lè dá àwọn ọmọ wa lẹ́jọ́, Ọlọ́run nìkan ló le ṣeé. Nínú èyí a rí ìtùnú púpọ̀: "Onídájọ́ gbogbo ayé kì yó a ṣe èyí tó tọ́? (Jẹnẹsisi 18:25b).
English
Kínni àwọn òbi Kristẹini gbọ́dọ̀ ṣe tí wọ́n bá ni ọmọkùnrin onínàákúnà (tàbí ọmọbìnrin)?