settings icon
share icon
Ibeere

Kínni orísun ẹ̀yà oríṣiríṣi?

Idahun


Bíbélì kò sọ fún wa lẹ́kúnrẹ́rẹ́ orísun oríṣiríṣi "ẹ̀yà" tàbí "àwọ̀" tí ènìyàn ní. Ní tòtọ́ọ́, ẹ̀yà kan péré ló wà—tíí ṣe ẹ̀yà ènìyàn. Nínú ẹ̀yà ènìyàn lati rí oríṣiríṣi àwọ̀ àtí àbùdá ara míìrán. Àwọn kan wòó wípé ìgbà tí Ọlọ́run da èdè wọn rú ní ilé-ìṣọ́ Bábélì (Jẹnẹsisi 11:1-9), Òun tún ṣẹ̀dá oríṣi ẹ̀yà pẹ̀lú. Ó ṣeé ṣe kí Ọlọ́run yí àwọn àbùdá jẹ̀nẹ́tiki àjogúnbá padà láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn yè nínú àgbègbè yóówù tí a bá dá wọn sí, fún àpẹẹrẹ, àwọ̀ ara dúdú tí ọmọ Afíríkà lè fara gba oru tí ó pọ̀ ní ilẹ́ Afíríkà. Gẹ́gẹ́ bíi àfojúsùn yìí, Ọlọ́run da èdè wọn rú, tí ó fa ìyapa lédè, tí ó sì jẹ́ ohun tí ó mú kí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ sí òmíràn wà ní ìlànà pẹ̀lú ibi tí wọn yóò máa gbé. Bí ó tilẹ́ ṣeé ṣe, kò sí ìdí l'ẹ́kúnrẹ́rẹ́ nípa àfojúsùn yìí nínú Bíbélì. Kò sí ibi tí a ti sọ nípa ẹ̀yà/ àwọ̀" ara ní ìbámu pẹ̀lú ilé-ìṣọ́ Bábélì.

Lẹ́yìn ìkún omi, tí àwọn èdè míìrán wà, àwọn ẹgbẹ́ tí ó ńsọ èdè kańáà, kó lọ pẹ̀lú àwọn míìrán tí ó ńsọ irú èdè náà. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, àwọn àkójọ gíìnì fún ẹgbẹ́ kan ní pàtó dínkù gan-an bí ẹgbẹ́ náà kò ṣe ní gbogbo àkójọpọ̀ ènìyàn láti darapọ̀mọ́. Ìbálòpọ̀ láàrin mọ̀lẹ́bí ṣẹlẹ̀, nígbàtí ó yá àwọn àbùdá kan wá bẹ̀rẹ̀ sí ní farahàn láàrin àwọn ẹgbẹ́ wọ̀nyìí (gbogbo èyítí ó wà, tí ó sì ṣeé ṣe nńú kóòdù jẹ̀nẹ́tiki náà). Bí ìbálòpọ̀ láàrin mọ̀lẹ́bí ṣe ńṣẹlẹ̀ láti ìran dé ìran, àwọn àbùdá náà ńdínkù, títí tí àwọn ènìyàn tí ó ni èdè kańnáà wá ní àwọn àwọn àbùdá kańnáà.

Àlàyé míìrán ni wípé Ádámù àti Éfà ní àbùdá tí ó le bí dúdú, àwọ̀ ilẹ̀ àti funfun (pẹ̀lú àwọn nǹkan míìrán láàrín àwọn èyí). Èyí yóò jọ bí àwọn tọkọtayà ẹ̀yà ọ̀tọ̀tọ̀ ṣe máa ńní àwọn ọmọ tí àwọ̀ wọn yàtọ̀ sí ara wọn. Nígbàtí ó jẹ́ wípé ó wu Ọlọ́run láti jẹ́ ki ènìyàn ní oríṣiríṣi ìrísí, ó dára wípé Ọlọ́run yóò ti fún Ádámù àti Éfà ní agbára láti lè bí àwọn ọmọ tí àwọ̀ wọn yàtọ̀ sí ara wọn. Lẹ́yìn ìgbà náà, Nóà àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ọkùnrin tí Nóà bí àtí àwọn ìyàwó wọn—gbogbo wọ́n jẹ́ ènìyàn mẹ́jọ tí ó ye ìkún omi náà (Jẹnẹsisi 7:13). Bóyá, àwọn ìyàwó ọmọ Nóà jẹ́ ẹ̀yà tó yàtọ̀. Ó tún ṣeé ṣe wípé ìyàwó Nóà wá láti ẹ̀yà tó yàtọ̀ sí ti Nóà. Bóyá, àwọn mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ jẹ́ ẹyà tí ó yàtọ̀ sí ara wọn, èyítí ó túmọ̀ sí wípé wọ́n ní ohun tí wọ́n fi lè bí ọmọ tí ẹ̀yà wọn yàtọ̀ sí ara wọn. Ohun yóò wù tí àlàyé náà lè jẹ́, abala tí ó ṣe pàtàkì ni wípé ẹ̀yà kan náà ni gbogbo wa, Ọlọ́run kańnáà ló dá gbogbo wa, ìdí kan náà ni a sì fi dá gbogbo wa— láti fi ògo fún-Òun.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni orísun ẹ̀yà oríṣiríṣi?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries