Ibeere
Ṣé ọ̀run-àpáàdì jẹ́ òtítọ́? Ṣé ọ̀run-àpáàdì jẹ́ ayérayé?
Idahun
Ó dùn mọ́ ni wípé ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ni ó gbàgbọ́ nínú wíwà ọ̀run ju àwọn tí ó ìgbàgbọ́ nínú wíwà ọ̀run-àpáàdì lọ. Ní ìbáamu pẹ̀lú Bíbélì, bí ó tilẹ̀ jẹ wípé, ọ̀run-àpáàdì jẹ́ òtítọ́ bíi ọ̀run. Bíbélì ṣe àfihàn àti àtúpalẹ̀ ẹ̀kọ́ náà wípé ọ̀run-àpáàdì wà l'óòtítọ́, ibi tí à ńrán àwọn ìkà/aláìgbàgbọ́ lọ lẹ́yìn ikú. Gbogbo wa ti ṣẹ̀ sí Ọlọ́run (Romu 3:23). Ìjìyà tí ó tọ́ fún ẹ̀ṣẹ̀ yẹn ni ikú (Romu 6: 23). Nígbàtí ó jẹ́ wípé gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa lòdì sí Ọlọ́run (Orin Dafidi 51:4), àti wípé bí Ọlọ́run se jẹ́ ẹni àìlópin àti ayérayé, ìjìyà fún ẹ̀ṣẹ̀, ikú, gbọdọ̀ jẹ́ àìlópin àti ayérayé pẹ̀lú. Ọ̀run-àpáàdì ni ikú aláìlópin àti ayérayé tí a ti jèrè nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa.
Ìjìyà ìkà òkú ní ọ̀run-àpáàdì ni a ṣe àpèjúwe rẹ̀ ní "iná ayérayé" jákèjádò Bíbélì (Matteu 25:41), "iná àjóòkú" (Matteu 3:12), "ìtìjú àti ẹ̀gàn àìnípẹ̀kun" (Daniẹli 12:2), ibi tí "iná náà kì síì í kú" (Marku 9:44-49), ibi "oró" àti "iná" (Luku 16:23-24), "ìparun ayérayé" (2 Tẹsalonika 1:9), ibi tí "èéfín oró wọn sì ńlọ sókè títí láíláí" (Ifihan 14:10-11), àti "adágún iná tí ńfi súfúrù jó" níbití a ó ti dá àwọn ìkà "l'óró t'ọ̀sán-t'òru láí àti láíláí (Ifihan 20:10).
Ìjìyà àwọn ìkà ní ọ̀run-àpáàdì kò l'óòpin gẹ́gẹ́ bí àlàáfíà òdodo ni ọ̀run. Jésù tìkararẹ̀ tọ́ka síi wípé ìjìyà ní ọ̀run-àpáàdì jẹ́ àìnípẹ̀kun bíi ìyè ní ọ̀run (Matteu 25:46). Àwọn ìkà wà l'ábẹ́ ìrunú àti ìbínú Ọlọ́run títí láíláí. Àwọn tí ó wà ní ọ̀run-àpáàdì yóò mọ ìdájọ́ Ọlọ́run tòótọ́ (Orin Dafidi 76:10). Àwọn tí ó wà ní ọ̀run-àpáàdì yóò mọ̀ wípé ìjìyà wọn ni àti wípé àwọn nìkan l'óni ẹbí (Deutarọnọmi 32:3-5). Bẹ́ẹ̀ni, ọ̀run-àpáàdì wáà. Bẹ́ẹ̀ni, ọ̀run-àpáàdì jẹ́ ibi oró àti ìjìyà tó wà láí àti láíláí, tí kò sì l'ópin. Ìyìn ní fún Ọlọ́run wípé, nípasẹ̀ Jésù, a le bọ́ lọ́wọ́ ikú ayérayé yìí (Johannu 3:16, 18, 36).
English
Ṣé ọ̀run-àpáàdì jẹ́ òtítọ́? Ṣé ọ̀run-àpáàdì jẹ́ ayérayé?