Ibeere
Ṣé àwọn ènìyàn tí ó wà l'ọ́ọ̀run lè wo ilẹ̀ kí wọ́n sì rí àwa tí ó sì wa l'áyé?
Idahun
Àwọn kan rí èrò nínú Heberu 12:1 wípé àwọn ènìyàn tí ó wà l'ọ́ọ̀run lè wo ilẹ̀ kí wọ́n sì rí wa: "Nítorínà bí a ti fi àwọsánmọ̀ tí ó kún tó báyìí fún àwọn ẹlẹ́rìí yí wa ká..." Àwọn "ẹlẹ́rìí" ni àkójọ àwọn akọni nínú ìgbàgbọ́ nínú Heberu 11, àti wípé wọ́n "yí wa ká" fún àwọn olùwòye láti mọ àwọn akọni (àti ó ṣeé ṣe àwọn ènìyàn yòókù) tí ó ńwò wá láti ọ̀run.
Èrò wípé àwọn ènìyàn ńwo ilẹ̀ láti ọ̀run láti ríi wípé ohun tí à ńṣe papọ̀ mọ́ àṣà tí ó gbajúmọ̀. Ṣùgbọ́n, bí a ti le fẹ́ èrò wípé àwọn olùfẹ́ tí ó ti kú ńwò wá tó, kìí ṣe ohun tí Heberu 12:1 ńkọ́ wa. Dídúro lórí Heberu 11, òǹkọ̀wé náà bẹ̀rẹ̀ láti fa àwọn kókó ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan yọ (ìdí nìyí tí orí 12 se bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú "Nítorínà"). Àwọn "ẹlẹ́rí" náà ni àwọn ènìyàn tí Ọlọ́run kansáárásí fún ìgbàgbọ́ wọn nínú orí 11, ọ̀pọ̀ irú ènìyàn yìí wà ní ọ̀run. Ìbéèrè náà ni, ọ̀nà wo ni wọ́n ṣe jẹ́ "ẹlẹ́rí"?
Ìtumọ̀ Heberu 12:1 tí ó tọ́ ni wípé àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó ńse "ẹlẹ́rí ńlá" jẹ́ ẹlẹ́rí sí iye ìgbé ayé nípa ìgbàgbọ́. Àwọn ìtàn Májẹ̀mú Láéláé fún wa ni ẹ̀rí i ìbùkún yíyan ìgbàgbọ́ dípò ẹ̀rù. Láti ṣe àyọsọ ìbẹ̀rẹ̀ Heberu 12:1, "Ìgbà tí a ní ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ìfihàn ìgbàgbọ́ tí a ti dánwò..." Níbáyìí, kìí ṣe wípé àwọn ènìyàn wa l'ọ́run tó ńwò wá (bí ẹni wípé ayé wa ńdùn ní ilé-ayé tàbí wọn kò ní ohun gidi láti ṣe!), ṣùgbọ́n àwọn tó ti lọ ṣáájú wa ti fi àpẹẹrẹ tó ṣeé gbáralé lélẹ̀ fún wa. Àkọsílẹ̀ ìgbé-ayé wọ́n ńjẹ̀rí sí ìgbàgbọ̀ àti Ọlọ́run àti òtítọ́.
Heberu 12:1 tẹ̀síwájú, "ẹ jẹ́ kí a pa ohun ìdíwọ́ gbogbo tì sí apákan, àti ẹ̀ṣẹ̀ tí ó rọrùn láti dì mọ́ wa, kí á sì maa fi súré ìje tí a gbé ka iwájú wa." Nítorí ìgbàgbọ́ àti ìfaradà àwọn onígbàgbọ́ tó ṣaájú wa lọ, à ní ìmísí láti dúró ṣinṣin nínú eré ìje ìgbàgbọ́ wa. A tẹ̀lé àpẹẹrẹ Abrahamu àti Mose àti Rahabu àti Gideoni àti abbl.
Àwọn ènìyàn tọ́kasí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ tó dárúkọ àwọn arákùnrin rẹ̀ nínú Luku 16:28 gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí fún àwọn ọkàn tó ti lọ (nínú isà òkú, ó kéré jù) le rí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ní ilé-ayé. Ṣùgbọ́n, ẹsẹ̀ àyọkà yìí kò sọ wípé ọlọ́rọ̀ náà le rí àwọn arákùnrin rẹ̀; ó mọ̀ wípé òun ni àwọn arákùnrin, ó sì mọ̀ wípé aláìgbàgbọ́ ni wọ́n. Bákannáà, àwọn ènìyàn ló Ifihan 6:10 gẹ́gẹ̀ bí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí: àwọn ajẹ́rìíkú ìpọ́njú ké sí Ọlọ́run láti gbẹ̀san ikú wọn. Bákannáà, ẹsẹ àyọkà yìí kò sọ ohun kankan nípa àwọn ajẹ́rìíkú wọ́n tí ńrí àwọn ènìyàn ní ilé-ayé; ó kàn ńsọ wípé àwọn mọ̀ wípé àwọn l'ẹ́tọ́ sí ìdájọ́ wọ́n sì fẹ́ kí Ọlúwa gbé ìgbésẹ̀.
Bíbélì kò sọ ní pàtó pé àwọn ènìyàn tó wà l'ọ́run kò lè wò wá, fún ìdí èyí a kò jẹ́ gbàá bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, kò ṣeé ṣe wípé wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí àwọn ènìyàn tí ó wà l'ọ́run ní ohun míìrán tí wọ́n ńse bíi sísin Ọlọ́run àti gbígbádùn àwọn ògo ọ̀run.
Bóyá àwọn tí ó wà l'ọ́run lè wo ilẹ̀ kí wọ́n sì rí wa tàbí bẹ́ẹ̀kọ́, a kò sá eré ìje wa fún wọn. À ńretí ìfọwọ́si wọn tàbí t'ẹ́tí sí ìyìn wọn. Heberu 12:2 fi ojú sọ́nà níbi tí ó yẹ: "Kí á máa wo Jésù olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláàṣepé ìgbàgbọ́ wa." Jésù ni ìrètí ìbùkún wa, kò sí ẹlòmíràn (Titu 2:13).
English
Ṣé àwọn ènìyàn tí ó wà l'ọ́ọ̀run lè wo ilẹ̀ kí wọ́n sì rí àwa tí ó sì wa l'áyé?