Ibeere
Ṣé nǹkàn bẹ́ẹ̀ wáà tí ó ńjẹ́ òtítọ́ pátápátá/òtítọ́ káríayé?
Idahun
Ní ọ̀nà láti ní òye nípa òtítọ́ pátápátá tàbí òtítọ́ káríayé, a gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìtumọ̀ òtítọ́. Òtítọ́, gẹ́gẹ́ bíi àkójọ ọ̀rọ̀ fún ìtumọ̀, ni "Fífaramọ́ òtítọ́ àti òdodo; àṣàyàn ọ̀rọ̀ tí a jẹ́rìsí tí a sì gbà wípé òtítọ́ ni". Àwọn ènìyàn kan yóò wípé kò sí ìṣẹ̀lẹ̀ òtítọ́, ìmọ̀lára àti èròǹgbà nìkan ni ó wà. Àwọn míìrán yóò jiyàn wípé àwọn òtítọ́ pátápátá àti òdodo kan wà.
Àfojúsùn kan sọ wípé kò sí òtítọ́ kan tí ó lè jẹ́ pátápátá. Àwọn tí wọ́n tẹ̀lé àfojúsùn yìí gbàgbọ́ wípé ohungbogbo nííṣe pẹ̀lú ohun míìrán, nítorí náà kò lè sí òtìtọ́ tí ó jẹ́ pátápátá. Fún ìyẹn, kò sí àwọn ìhùwàsí òtítọ́ pátápátá ní ìkẹhìn, kò sí àṣẹ fún pípinnu bóyá ìwà kan bá èyí tí ó tọ́ tàbí tí kò tọ́, dára tàbí kò dára. Àfojúsùn yìí yọrí sí "ẹ́tíkìì ìṣẹ̀lẹ̀," ìgbàgbọ́ wípé ohun tí ó tọ́ tàbí tí kò tọ́ tí ó nííṣe pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀. Kò sí ohun tí ó tọ́ tàbí ohun tí kò tọ́, nítorínáà, ohunkóhun tí a lérò wípé ó tọ́ ní àkókò náà, ní ìbámu pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni ó tọ́. Bẹ́ẹ̀ni, òfin ìṣesí ìṣẹ̀lẹ̀ yọrí sí èrò kúkúrú "ohun tí ó bá dùn mọ́ni" ati ìgbé-ayé bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀, tí ó le fa àkóbá ńlá fún àwùjọ àti àwọn ènìyàn. Èyí nííṣe pẹ̀lú ti òde òní, tí ó fi àyè gba àwùjọ tí ó ka àwọn àbùdá, ìgbàgbọ́, ìgbé-ayé, ati òtítọ́ sí bíi ohun tí ó ṣe pàtàkì bákannáà.
Àfojúsùn míìrán sọ wípé àwọn tí ó dájú pátápátá l'ótítọ́ wà àti àwọn òṣùwọ̀n tí ó ṣọ ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ àti ohun ti kìí ṣe òtítọ́. Nítorí náà, a lè rí ìwà bíi ohun tí ó tọ́ tàbí tí kò tọ́ nípa bí wọ́n ṣe kún ojú òsùwọ̀n wọ̀n yẹn sí. Bí kò bá sí òtítọ́ pátápátá, kò sí èyí tí ó dájú, rúkèrúdò yóò ṣẹlẹ̀. Wo òfin lálá tó ròkè, fún àpẹẹrẹ. Bí kìí bá ṣe òtítọ́ pátápátá ni, kò bá má dá wa lójú wípé a lè dúró tàbí jókòó lójú kan náà títí a ó fi pinnu láti sún Tàbí bí àròpọ̀ méjì pẹ̀lú méjì kò bá jẹ́ mẹ́rin nígbagbogbo, àwọn ipa lórí ọ̀làjú lè burú jáì. Àwọn òfin sáyẹ́ǹsì àti ẹ̀kọ́ ohun ti a lè fójú rí (physics) kò ní wúlò, ọrọ̀-ajé kò ní ṣeé ṣe. Gbogbo rẹ̀ ò bá ti fọ́júpọ̀ tó! Adúpẹ́ pé, àròpọ̀ méjì pẹ̀lú méjì jẹ́ mẹ́rin. Òtítọ́ pátápátá wà, a lè wa rí, ó sì lè yé wa.
Kò mú ọpọlọ wá láti ṣọ wípé òtítọ́ pátápátá kò sí. Síbẹ̀, lónìí, àwọn ènìyàn ńfaramọ́ àwọn àṣà rẹletífísíìmù tí ó tẹ́ńbẹ́lú òtítọ́ pátápátá. Ìbéèrè pàtàkì tí ó yẹ kí á bi àwọn ènìyàn tí wọ́n sọ wípé "kò sí òtítọ́ pátápátá" ni yìí: "Ǹjẹ́ ìyẹn dáa yín lójú pátápátá?" Tí wọ́n bá sọ wípé "bẹ́ẹ̀ni", wọ́n ti sọ òdodo ọ̀rọ̀—tí ó túmọ̀ sí wípé òtítọ́ pátápátá wà. Wọ́n ńsọ wípé òdodo wípé kò sí òtítọ́ pátápátá gan an ni òtítọ́ pátápátá kan soso.
Yàtọ̀ sí ìṣòro títako ara ẹni, àwọn ìṣòro gbòógì míìrán wáà tí a gbọ́dọ̀ borí kí á tó lè ṣọ wípé kò sí òtítọ́ pátápátá tàbí òtítọ́ káríayé. Ọ̀kan nínú rẹ̀ ni wípé ènìyàn ní gbèdéke ìmọ̀ àti èrò, nítorí náà, kò lè fi ọpọlọ sọ ọ̀rọ̀-òdì tí ó jẹ́ òdodo pátápátá. Ènìyàn kan kò lè fi ọpọlọ sọ wípé, " Kò sí Ọlọ́run (bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀), nítorí, ní ìlànà láti sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, yóò nílò láti ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìmọ̀ nípa àgbáyé láti ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ dé òpin. Nígbàtí èyí kò ṣeé ṣe, èyí tí ènìyàn lè fi ọpọlọ sọ jù ni wípé "Pẹ̀lú ìmọ́ kúkúrú tí mo ní, nkò gbà pé Ọlọ́run wà."
Ìṣòro míìrán tí ó wà pẹ̀lú sísẹ́ òtítọ́ pátápátá/òtítọ́ àgbáyé ni wípé ó kùnà láti gbé bí ohun tí a mọ̀ láti jẹ́ òtítọ́ nínú ẹ̀rí ọkàn wa, nínú àwọn ìrírí wa, àti ohun tí á ńrí nínú ayé tòótọ́. Bí kò bá sí ohun kan tí à ńpè ní òtítọ́ pátápátá, nígbà náà kò sí ohun tí ó tọ̀nà tàbí tí kò tọ̀nà nípa ohunkóhun. Ohun tí ó lè "tọ́" fún ìwọ, kò túmọ̀ wípé ó "tọ́" fún èmi. Nígbàtí tí a bá wòó lórèfé, irú rẹletífísímùù yìí kò jọ wípé o fani mọ́ra, ohun tí ó túmọ̀ sí ni wípé kí gbogbo ènìyàn la òfin ti rẹ̀, tí ó lè máa gbé nípa rẹ̀, tí ó sì ńṣe ohun tí ó rò wípé ó tọ́. Láì lè yẹ̀bá fún, èrò ènìyàn kan nípa ohun tí ó tọ̀nà kò ní pẹ́ kọlu ti ẹlòmíràn. Kíló ṣẹlẹ̀ bí ó bá "tọ́" fún mi láti gbójú kúrò fún iná fún dídarí ọkọ lójú pópónà, bí wọ́n tilẹ̀ tan iná pupa? Èmi fi ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ sínu ewu. Tàbí èmi lè rò wípé ó tọ́ fún mi láti jí nǹkan lọ́dọ̀ rẹ, kí o sì rò wípé kò tọ́. Ní kedere, ìfagagbága wà láàrin òṣùwọ̀n ohun tí ó yẹ àti èyí tí kò yẹ. Bí kò bá sí òtítọ́ pátápátá, kò sí òṣùwọ̀n ohun tí ó tọ́ tàbí tí kò tọ́ tí a ma jíhìn fún, nígbà náà a kò lè ní àrídájú ohunkóhun. Àwọn ènìyàn yóò ní òmìnira láti ṣe ohunkóhun tí ó bá wù wọ́n—ìpànìyàn, ìfipabánilòpọ̀, olè jíjà, irọ́, ìrẹ́nijẹ, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ́, kò sí ohun tí ó burú nípa àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ . Kò lè sí ìjọba, kò lè sí òfin, kò lè sí ìdájọ́ òdodo, nítorí wípé ènìyàn kò lè sọ wípé ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ní ẹ̀tọ́ láti ṣe òṣùwọ̀n àti láti fi pá mú àwọn ìyókù. Ayé tí kò ní òtítọ́ pátápátá yóo jẹ́ ayé tí a lè rò wípé ó burú jùlọ.
Ní abala ti ẹ̀mí, irúfẹ́ àfiwé yìí yọrí sí rúdurùdu ẹ̀sìn, tí kò sí ẹ̀sìn tòótọ́, tí kò sì sí ọ̀nà tí a lè fi ni ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Gbogbo ẹ̀sìn ló máa jẹ́ èké nítorí wípé gbogbo wọn ló ńjẹ́wọ́ pátápátá nípa ayé tí ó ńbọ̀. Kìí ṣe nǹkan tí kò wọ́pọ̀ lónìí fún àwọn ènìyàn láti gbàgbọ́ wípé ẹ̀sìn méjì tí ó tako ara wọn pátápátá lè jọ jẹ́ "òtítọ́" bákan náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé àwọn méjèèjì ló ńsọ wípé àwọn làwọn ní ọ̀nà kan ṣoṣo tí ó lọ sí ọ̀run tàbí kí wọ́n kọ́ "òtítọ́" méjì tí ó tako ara wọn pátápátá. Àwọn ènìyàn tí kò gbàgbọ́ nínú òtítọ́ pátápátá kọ ẹ̀yìn sí àwọn ìjẹ́wọ́ọ́ yìí, tí wọ́n sì gba ẹ̀kọ́ àgbáyé tí ó ṣé faramọ́ èyí tí ó kọ́ wa wípé gbogbo ẹ̀sìn jẹ́ ọ̀kan, àti wípé gbogbo ọ̀nà ló lọ sí ọ̀run. Àwọn ènìyàn tí ó gba àfojúsùn yìí nípa ayé ṣe àtakò àwọn Kristiẹni oníhìnrere tí ó gbà Bíbélì gbọ́ gidigidi nígbàtí ó sọ wípé Jésù ni "ọ̀nà, òtítọ́ àti iyè" àti wípé Òun ni ìfarahàn òtítọ́ àti ọ̀nà kan ṣoṣo tí a fi lè dé ọ̀run (Johannu 14:6).
Ìfaradà ti di ọ̀rọ̀ pàtàkì kan fún àwùjọ tí ó tẹ̀lé èyí tí ó lajú, èyí nì nǹkan pátápátá, àti wípé nítorí náà, àìní-ìfaradà jẹ́ ibi kan ṣoṣo. Ìgbàgbọ́ yóòwù tí a kò lè tẹ̀ —ní pàtàkì ìgbàgbọ́ nínú òtítọ́ pátápátá—jẹ́ ohun tí à ńwò bíi àìní-ìfaradà, olórí ẹ̀ṣẹ̀. Àwọn tí ó sẹ́ òtítọ́ pátápátá yóò sọ ní ọ̀pọ̀ ìgbà wípé ó yẹ láti gbà ohun tí a fẹ̀ gbọ́, níwọ̀n ìgbà tí a kò gbìyànjú láti ti ìgbàgbọ́ wa mọ́ ẹlòmíràn lọ́rùn. Ṣùgbọ́n, àfojúsùn yí tìkalárá rẹ̀ jẹ́ ìgbàgbọ́ nípa ohun tí ó dára àti èyí tí kò dára, ó dájú wipé àwọn tí ó sì di àfojúsùn yìí mú ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà má ńgbìyànjú láti tìí mọ́ ẹlòmíràn lọ́rùn. Wọ́n dá òṣùwọ̀n fún ìhùwàsí tí wọ́n dúró lé lórí wípé àwọn yókù gbọ́dọ̀ tẹ̀lé, nípa bẹ́ẹ̀ wọ́n ja òfin ohun tí wọ́n sọ wípé àwọn gbéró gangan—ipò míìrán tí ó tako ara rẹ̀. Àwọn tí ó di irú ìgbàgbọ́ báyìí mú kò kàn fẹ́ jẹ́ kí àwọn jínhìn fún ìṣe wọn. Bí òtítọ́ pátápátá bá wà, nígbà náà òṣùwọ̀n lẹ́kúnrẹ́rẹ́ wà fún ohun tí ó tọ́ àti èyí tí kò tọ́, àwa yóò jínhìn fún àwọn òṣùwọ̀n wọ̀nyìí. Àwọn ìjínhìn yìí ni ohun tí àwọn ènìyàn ńkọ̀ sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá kọ òtítọ́ pátápátá.
Sísẹ́ òtítọ́ pátápátá/òtítọ́ àgbáyé àtí àfiwé àṣà tí ó wá pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́ àyọrísí iṣẹ́ ọpọlọ ní àwùjọ tí ó ti fa ẹ̀kọ́ ẹfolúṣàn mọ́ra gẹ́gẹ́ bí àlàyé fún ìgbé-ayé. Bí àwọn oníṣẹ̀dá ẹfolúṣàn bá jẹ́ òtítọ́, ayé kò ní ìtumọ̀ nígbà náà, a kò ní èrèdí, kò lè sí ohun tí ó tọ́ tàbí tí kò tọ́. Nígbà náà ni ènìyàn ní òmìnira láti gbé ayé bí ó ti wùú, kò sí ní jínhìn fún ẹnikẹ́ni nípa àwọn ìṣe rẹ̀. Síbẹ̀ kò sí bí àwọn ènìyàn tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀ ti lè sẹ́ ìwàláàyé àti òtítọ́ pátápátá, wọ́n yóò ṣì padà dúró níwájú Rẹ̀ ní ìdájọ́ ní ọjọ́ kan. Bíbélì sọ wípé "...ohun tí a lè mọ̀ níti Ọlọ́run ó farahàn nínú wọn; nítorí Ọlọ́run ti fi í hàn fún wọn. Nítorí ohùn rẹ̀ farasin láti ìgbà dídá ayé, a rí wọn gbangba, a ńi òye ohun tí a dá m ọ̀ ọ, àní agbára àti ìwà—Ọlọ́run rẹ̀ ayérayé, kí wọ́n kí ó lè wà lí àìríwí: Nítorí ìgbàtí wọ́n mọ Ọlọ́run, wọn kò yìn ín lógo bí Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ni nwọ̀n kò sì dúpẹ́; ṣùgbọ́n èrò ọkàn wọ́n di asàn , a sì mú ọkàn òmùgọ̀ wọn ṣókùnkùn. Wọ́n ń pe ara wọn ní ọlọgbọ̀n, wọ̀n di àṣiwèrè" (Romu 1:19-22).
Ǹjẹ́ ẹ̀rí kankan wà nípa wíwà òtítọ́ pátápátá? Bẹ́ẹ̀ni. Lákọ́kọ́, ẹ̀rí ọkàn ènìyàn wà, pé "nǹkan" kan wà tí ó dájú nínú wa tí ó sọ fún wa wípé ayé yẹ kí ó jẹ́ ọ̀nà tí ó dájú, wípé àwọn nǹkan kan tọ́, nígbà tí àwọn kan kò sì tọ́. Ẹ̀rí ọkàn wa fí dáwa lójú wípé nǹkan kan kò yẹ nípa ìjìyà, ebi, ìfipabánilòpọ̀, ìrora, àti ibi, ó sì jẹ́ kò yé wa wípé ìfẹ́, ìfifúnni, àánú, àti àlàáfíà jẹ́ ohun rere tí ó yẹ kí á tiraka fún. Èyí jẹ́ òtítọ́ àgbáyé nínú gbogbo àṣà ní ìgbà gbogbo. Bíbélì ṣe àpèjúwe iṣẹ́ ẹ̀rí ọkàn ènìyàn nínú ìwé Romu 2:14-16: "Nítorí nígbàtí àwọn Kèfèrí, tí kò lí òfin, bá ṣe ohun tí ó wà nínú òfin nípa ẹ̀dá, àwọn wọ̀nyí tí kò lí òfin, jẹ́ òfin fún ara wọn: Àwọn ẹnití ó fihàn pé, a kọ̀wé iṣẹ́ òfin sí wọn lí ọkàn, tí ọkàn wọ̀n sí njẹ́ wọn lẹ́rí, tí ìrò wọ́n láàrin ara wọ̀n sí ńfi wọ̀n sùn tàbí tí ó ńgbè wọ̀n. Lí ọjọ́ nà nígbàtí Ọlọ́run yíó ti ipa Jésù Krístì ṣe ìdájọ́ àṣírí ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere mi".
Ẹ̀rí kejì fún ìwàláàyè òtítọ́ pátápátá ni sáyẹ́nsì. Sáyẹ́nsì kàn jẹ́ ìlépa ọgbọ́n, ẹ̀kọ́ ohun tí a mọ̀ àti ìpòǹgbẹ làti mọ̀ si. Nítorí náà, gbogbo ẹ̀kọ́ sáyẹ́nsì nípa ìwúlò gbọ́dọ̀ dúró lé lórí ìgbàgbọ́ wípé àwọn ìlépa tí ó dájú wà nínú ayé àti wípé a lè ṣe àwárí àti ìfìdímúlẹ̀ àwọn nǹkan tí ó dájú. Láì sí nǹkan tí ó dájú pátápátá, kínni i bá wà láti kọ́ nípa rẹ̀? Báwo ni a ò bá ṣe mọ̀ wípé àwọn ìwádí sáyẹ́nsì jẹ́ òtítọ́? Bẹ́ẹ̀ni, a ṣe àgbékalẹ̀ àwọn òfin sáyẹ́nsì gangan lórí wíwà òtítọ́ pátápátá.
Ẹ̀rí kẹta fún ìwàláàyè òtítọ́ pátápátá/òtítọ́ àgbáyé ni ẹ̀sìn. Gbogbo àwọn ẹ̀sìn ló gbìyànjú láti fi ìtumọ̀ àti àkàwé sí ayé. A bí wọn láti inú ìpòǹgbẹ fún nǹkan tí ó ju kí á gbé nì kan lọ. Nípàsẹ̀ ẹ̀sìn, ènìyàn máa ńwá Ọlọ́run, ìrètí fún ọjọ́ ọ̀la, ìdáríjì fún ẹ̀ṣẹ̀, àlàáfíà láàrin làálàá, àti ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tí ó jìn. Ẹ̀sìn jẹ́ ẹ̀rí tòòtọ́ fún wípé irú ìràn ènìyàn kìí kàn ṣe ẹranko gígá tí ó jẹyọ. Ó jẹ́ ẹ̀rí èrèdí tí ó ga àti ìwàláàyè ti ara ẹni tí ó níi ète, èyí tí Ẹlẹ́dá gbìn sí ènìyàn lọ́kàn, ìpòngbẹ láti fẹ́ mọ̀ Òun si. Tí ó bá jẹ́ òdodo wípé Ẹlẹ́dá wà, nígbà náà Òun di ọṣùwọ̀n fún òtítọ́ pátápátá, àṣẹ Rẹ̀ ni ó sì gbé òtítọ́ náà kalẹ̀.
Ó jẹ́ nǹkan ayọ̀ wípé, irú Ẹlẹ́dá bẹ́ẹ̀ wà, Òun sì fi òtítọ́ Rẹ̀ hàn sí wa nínú Bíbélì, tíí ṣe Ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Mímọ òtítọ́ pátápátá/òtítọ́ àgbáyé lè ṣeé ṣe nìkan nípa ìbáṣepọ̀ ẹlẹ́ní-kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú Ẹni tí ó pe ara Rẹ̀ ní Òtítọ́—Jésù Kristi. Jésù sọ wípé òun ni ọ̀nà kan ṣoṣo, òtítọ́ kan ṣoṣo, ìyè kan ṣoṣo àti ipasẹ̀ kan ṣoṣo sí Ọlọ́run (Johannu 14:6). Òdodo wípé òtítọ́ pátápátá wà tọ́ ka wa sí òtítọ́ wípé Ọlọ́run tí ó gajù lọ, tí ó dá ọ̀run àti ayé, tí ó sì fi ara Rẹ̀ hàn sí wa, láti lè jẹ́ kí á mọ̀ Òun fúnra wa nípasẹ̀ Jésù Krístì, ọmọkùnrin Rẹ̀. Èyí ni òtítọ́ pátápátá.
English
Ṣé nǹkàn bẹ́ẹ̀ wáà tí ó ńjẹ́ òtítọ́ pátápátá/òtítọ́ káríayé?