Ibeere
Kínni Bíbélì sọ nípa oyún ṣíṣẹ́?
Idahun
Bíbélì kò sọ nípa oyún ṣíṣẹ́ ní pàtó. Ṣùgbọ́n, àwọn àìníye ẹ̀kọ́ ni ó wà nínú Ìwé Mímọ́ tí ó fi ìpinnu Ọlọ́run hàn nípa oyún ṣíṣẹ́. Jeremiah 1:5 sọ fún wa wípé Ọlọ́run mọ̀ wá kí Òun tó dá wa nínú oyún. Orin Dafidi 139:13-16 sọ nípa iṣẹ́ ribiribi Ọlọ́run nínú ìṣẹ̀dá àti ìdàgbàsókè wa nínú oyún. Ẹksodu 21:22-25 sọ wípé ìjìyà kan náà—ikú—ni ó tọ́ sí ẹnití ó ṣe okùfà ikú ọmọ nínú oyún bíi fún ẹnití ó pànìyàn. Èyí túmọ̀ sí wípé Ọlọ́run rí ọmọ nínú oyún bíi èníyàn kan tí ó ti di àgbàlagbà. Fún Kristiẹni, oyún síṣẹ́ kìí ṣe ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ obìnrin láti yàn. Ó jẹ́ ọ̀rọ̀ ìyè àti ikú ènìyàn tí a dá ní àwòrán Ọlọ́run (Jẹnẹsisi 1:26-27; 9:6).
Àríyànjiyàn àkọ́kọ́ tí ó máa ńjẹyọ tí ó lòdì sí ipò Kristiẹni lórí oyún síṣẹ́ ni "Kínni yóò ṣẹlẹ̀ bí ó bá jẹ́ ìfipábánilòpọ̀ tàbí ìbálòpọ̀ láàrin mọ̀lẹ́bí ? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ohun ìtìjú ni láti lóyún nípa ìfipábánilòpọ̀ tàbí ìbálòpọ̀ láàrin mọ̀lẹ́bí , ṣé pípa ọmọ wá ni ìdáhùn ni? Àsìṣe kòlè jẹ́ ọ̀nà àbáyọ fún àsìṣe míìrán. Ọmọ tí á bi nípa ìfipábánilòpọ̀ tàbí ìbálòpọ̀ láàrin mọ̀lẹ́bí lè jẹ́ gbígbà fún àwọn ẹbí aláyọ̀ tí wọn kò tíì rí ọmọ ti wọn bí, tàbí kí ìyá rẹ̀ tọ́ọ. Lẹ́ẹ̀kànsii, ọmọ yìí jẹ́ aláìmọ̀kan pátápátá tí kò sì yẹ kí ó jẹ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ bàbá rẹ̀.
Àríyànjiyàn kejì tí ó maa ńjẹyọ lòdì sí ipò Krisiẹni lórí oyún síṣẹ́ ni "Bí ẹ̀mí ìyá bá wà nínú ewu ńkọ́?" Nítòótọ́, èyí ni ìbéérè tí ó ṣòro jù láti dáhùn lórí ọ̀rọ̀ oyún síṣẹ́. Àkọ́kọ́, kí á rántí wípé èyí jẹ́ ìdámẹ̀ẹ́wá ti ìdákan nínú ọgọ́rùn-ún oyún síṣẹ́ láyé òde òní. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin ni ó máa ńṣẹ́yún fún ìrọ̀rùn ara wọn ju láti bọ́ lọ́wọ́ ewu lọ. Ẹ̀ẹ̀kejì, kí á rántí wípé Ọlọ́run jẹ́ Ọlọ́run ìyanu. Òun lè pa ìyá àti ọmọ mọ́ nínú àìlera láìkàsí gbogbo ewu ìṣègùn tí ó ńkojú wọn. Ní ìkẹhìn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé, ìbéèrè yìí wà láàrín ọkọ, ìyàwó àti Ọlọ́run láti pinnu. Èyíkéyì tọkọ-taya tí ó ńla irú ìṣòro ńlá báyìí kọjá nílò láti gbàdúrà sí Olúwa fún ọgbọ́n (Jákọbu 1:5) láti mọ ohun tí Òun yóò fẹ́ kí wọ́n ṣe.
Ìdá máàrún dín ní ọgọ́rùn-ún (95) àwọn oyún ṣíṣẹ́ lóde òní ní íṣe pẹ̀lú àwọn obìnrin tí kò fẹ́ bímọ. Ó dín díẹ̀ ní ìdá máàrún (5) nínú ọgọ́ọ̀rún oyún ṣíṣẹ́ ni ó ṣẹlẹ̀ nítorí ìfipábánilòpọ̀, ìbálòpọ̀ láàrin mọ̀lẹ́bí tàbí ewu ìlera ìyá. Kódà nínú àwọn ìdá máàrún (5) nínú ọgọ́rùn ún náà, oyún ṣíṣẹ́ kòyẹ kí ó jẹ́ èrò àkọ́kọ́. Ìgbé-ayé ènìyàn nínú oyún yẹ fún gbogbo ipá láti gba ọmọ náà láàyè láti wáyé.
Fún àwọn tí ó ti ṣẹ́ oyún tẹ́lẹ̀, rántí wípé ẹ̀ṣẹ̀ oyún ṣíṣẹ́ náà kò kéré fún láti rí ìdáríjì gbà ju èyíkéyi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yóókù lọ. Nípa ìgbàgbọ́ nínú Kristi, a lè dáríi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ jìn. ( Johannu 3:16; Romu 8:1; Kolosse 1:14). Obìnrin tí ó ti ṣẹ́ oyún tẹ́lẹ̀, ọkùnrin tí ó ti gba obìnrin níyànjú láti ṣẹ́ oyún, tàbí dọ́kítà tí ó ti ṣẹ́ oyún kan rí—gbogbo wọn ni ó le rí ìdáríjì gbà nípa ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi.
English
Kínni Bíbélì sọ nípa oyún ṣíṣẹ́?