settings icon
share icon
Ibeere

Tani ó lè di ẹni ìgbàlà? Ṣé ẹnìkan lè di ẹni ìgbàlà?

Idahun


Jésù kọ́ni dáradára ní Johannu 3:16 wípé Òun yóò gba ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ nínú Òun là: "Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, tí ó fi Ọmọ bíbí Rẹ̀ kan soso fúnni, kí ẹnikẹ́ni tí ó ba gbàá gbọ́ má bàa ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àínìpẹkun." "Ẹnikẹ́ni" yìí ní ìwọ nínú àti gbogbo ènìyàn yòókù nínú ayé.

Bíbélì sọ wípé, bí ìgbàlà bá dálé agbára wa, kò sí ẹnití yóò là: "Gbogbo ènìyàn ni ó sá ti ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọ́run" (Romu 3:23). Orin Dafidi 143:2 ṣe àfikún,"Kò sí ẹnití o wà láàyè tí a ó dáláre níwájú rẹ." Romu 3:10 ṣe ìfidí múlẹ̀ rẹ̀,"Kò sí ẹnití íṣe olódodo, kò sí ẹnìkan."

A kò le gba ara wa là. Dípò bẹ́ẹ̀, a gbà wá là nígbàtí a gbàgbọ́ nínú Jésù Kristi. Efesu 2:8-9 kọ́ wa wípé, "Nítorí ore-ọ̀fẹ́ ni a ti fi gbà yín là nípa ìgbàgbọ́; àti èyíinì kì íṣe ti ẹ̀yin tìkarayín: ẹ̀bùn Ọlọ́run ni—kìí ṣe nípa iṣẹ́, kí ẹnikẹ́ni má bàa ṣògo." Nípa ore-ọ̀fẹ́ ni a fi gbà wá là, àti wípé ore-ọ̀fẹ́ nípa ìtumọ̀, ni a kò yẹ fún. A kò yẹ fún ìgbàlà; a kàn gbàá nípa ìgbàgbọ́.

Ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tó láti bo gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀ (Romu 5:20). Bíbélì kún fún àwọn àpẹẹrẹ ènìyàn tí a gbàlà kúrò nínú ìpìlẹ̀ ayé ẹ̀ṣẹ̀. Pọ́ọ̀lù apọsteli kọ̀wé sí àwọn onígbàgbọ́ tí wọn fi ìgbàkan gbé nínú orísi ipò ẹ̀ṣẹ̀, èyí tíí ṣe panságà, ìbọ̀rìsà, àgbèrè, ìbálòpọ̀ ọkùnrin sí ọkùnrin tàbí obìnrin sí obìnrin, olè, ojúkòkúrò, àti ìmutípara. Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù sọ fún wọn wípé, lórí ìgbàlà, "A ti wẹ̀ yín nù, ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti dá yín láre ní orúkọ Jésù Kristi Olúwa, àti nípa Ẹ̀mí Ọlọ́run wa" (1 Kọrinti 6:9-11).

Apọsteli Pọ́ọ̀lù tìkararẹ̀ ti jẹ́ onínúnibíni sí àwọn onígbàgbọ́, ó fi ọwọ́ sí ikú Stefanu (Iṣe àwọn Apọsteli 8:1) ó sì ńmú àwọn onígbàgbọ́ jù sínú túbú (Iṣe àwọn Apọsteli 8:3). Òun wá kọ̀wé lẹ́yìn náà,"Bí mo tilẹ̀ jẹ́ asọ ọ̀rọ̀-òdì lẹ́ẹ̀kan rí, àti onínúnibíni, àti eléwu ènìyàn; ṣùgbọ́n mo rí àànú gbà, nítorítí mo ṣe é ní àìmọ̀ nínú àìgbàgbọ́. Ore-ọ̀fẹ́ Olúwa wá sì pọ̀ rékọjá pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́, tí ńbẹ nínú Kristi Jésù. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ fún ìtẹ́wọ́gbà: Pé Kristi Jésù wá sí ayé láti gba ẹlẹ́ṣẹ̀ là; nínú àwọn ẹnití èmi jẹ́ pàtàkì" (1 Timoteu 1:13-15).

Ọlọ́run má ńyàn láti gba àwọn ẹni tí ó dàbí wípé kò yẹ là lẹ́kọ̀ọ̀kan láti mú ète Rẹ̀ ṣẹ. Ó gba olè kan là lórí igi àgbélébù pẹ̀lú ìṣẹ́jú kan láti fi gbé (Luku 23:42-43), onínúnibíni ìjọ (Pọ́ọ̀lù), apẹja tí ó ṣẹ́ẹ (Peteru), ológun Romu àti ìdílé rẹ̀ (Iṣe àwọn Apọsteli 10), ẹrú tí ó sá (Onisimu ni Filimoni), àti ọ̀pọ̀ míìrán. Kò sí ẹnìkan tó kọjá agbára Ọlọ́run láti gbàlà (wo Isaiah 50:2). A gbọ́dọ̀ dáhùn pẹ̀lú ìgbàgbọ́ kí á sì gba ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ayérayé Rẹ̀.

Tani ó lè di ẹni ìgbàlà? Ohun kan ló dájú – ìwọ le là, bí o bá gba Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà rẹ̀! Bí kò bá dá ọ lójú wípé o ti gba Jésù gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà rẹ, o lè dáhùn nísisìnyí pẹ̀lú àdúrà tí ó bá èyí mu:

"Ọlọ́run, mo mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí àti wípé èmi kò lè dé ọ̀run nípa àwọn iṣẹ́ rere mi. Ní bàyìí mo fi ìgbàgbọ́ mi sínú Jésù Krsti gẹ́gẹ́ bíi ọmọ Ọlọ́run ẹni tí ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ mi tí ó sì jí dìde kúrò nínú òkú láti fún mi ní ìyè ayérayé. Jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ mí jìn mí kí O sì ràn mí lọ́wọ́ láti gbé ayé fún Ọ. O ṣeun tí ó gbà mí tí o sì fún mi ní ìyè ayérayé."

Ti o ba fe gba jesu Kristi gbo gege bi olugbala re nikan, so awon oro won yi si Oluwa. Ranti wipe, gbigba adura yi tabi adura mi ran ko le gba o o la. O ni lati ni ireti ninu Jesu Kristi wipe o le dariji ese re ji o. Adura yi je eyi ti o file so fun Oluwa nipa igbagbo re ninu re, ki o si dupe fun idariji re.“ Oluwa, mo wipe elese ni mi. mo si mo wipe iya ayeraye to si mi fun ese mi.” Sugbon, mo ni ireti ninu Jesu Kristi gege bi olugbala. Mo mo n wipe iku ati ajinde re lo fun mi ni idariji ese. Mo ni ireti ninu Jesu, Jesu ni kan gege bi Olorun ni nikan ati olugbala mi. E se fun ore- ofe ati idariji ese mi- ebun ayeraye! Ami!

Nje o ti se ipinu fun Kristi nitoripe ohun ti o ti ka ninu oju ewe yi. To ba jebe, jowo te “Mo ti gba Kristi ni oni” ni abe.



English



Pada si oju ewe Yorùbá

Tani ó lè di ẹni ìgbàlà? Ṣé ẹnìkan lè di ẹni ìgbàlà?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries