Ibeere
Báwo ni mo ṣe le kún fún Ẹ̀mí Mímọ́?
Idahun
Ẹsẹ kan tí ó ṣe pàtàkì láti ni òye kíkún fún Ẹ̀mí Mímọ́ wà ní Johannu 14:16, níbi ti Jésù ti ṣe ìlérí wípé Ẹ̀mí yóò máa gbé nínú àwọn onígbàgbọ́ àti wípé gbígbé inú yìí yóò wà títí láíláí. Ó ṣe pàtàkì láti dá gbígbé inú Ẹ̀mí yàto sí kíkún fún Ẹ̀mí. Gbígbé inú Ẹ̀mí kìí ṣe fún àwọn onígbàgbọ́ kan tí a yàn, ṣùgbọ́n fún gogbo àwọn onígbàgbọ́. Ó ní iye àwọn ìtọ́kàsi Ìwé Mímọ́ tí wọn ṣe àtìlẹhìn fún àkótán yìí. Èkínní, Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ ẹ̀bùn fún gbogbo onígbàgbọ́ nínú Jésù láì dá ẹnìkan yàtọ̀, kò sì sí àwọn àmúyẹ kankan fún ẹ̀bùn yìí àyààfi ìgbàgbọ́ nínú Kristi (Johannu 7:37-39). Èkejì, a fún ni ní Ẹ̀mí Mímọ́ ní àkókò ìgbàlà (Efesu 1:13). Ìwé Galatia 3:2 tẹnumọ́ òtítọ́ yìí kan náà, wípé fífi èdìdí àti gbígbé inú Ẹ̀mí wáyé ní ìgbà gbígbàgbọ́. Ẹ̀kẹta, Ẹ̀mí Mímọ́ ńgbé nínú àwọn onígbàgbọ́ láíláí. A fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún àwọn onígbàgbọ́ bíi owó tí a san sílẹ̀, tàbí ṣíṣe àyẹ̀wò ògo ọjọ́ iwájú wọn nínú Kristi (2 Kọrinti 1:22; Efesu 4:30).
Èyí yàtọ̀ sí kíkún ni pẹ̀lú Ẹ̀mí tí Efesu 5:18 ńtọ́kasí. Àwa gbọ́dọ̀ jọ̀wọ́ ara wa fún Ẹ̀mí Mímọ́ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ fún Òun láti gbé wa wọ̀, ní òye yìí, kún wa. Ìwé Romu 8:9 àti Efesu 1:13-14 sọ wípé Òun ńgbé pẹ̀lú gbogbo onígbàgbọ́, ṣùgbọ́n a lè múu bínú (Efesu 4:30), tí a si lè paná iṣẹ́ Rẹ̀ nínú wa (1Tẹssalonika 5:19). Nígbà tí a bá gbà láti jẹ́ kí èyí ṣẹlẹ̀, àwa kìí írí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àti agbára Rẹ̀ nínú wa àti nípasẹ̀ wa. Láti kún fún Ẹ̀mí túmọ̀ sí òmìnira fún Òun láti gba gbogbo ìpín ayé wa, tí Òun ńdarí tí Òun si ńṣàkoso wa. Nígbànáà Òun le fi àgbara Rẹ̀ hàn nípasẹ̀ wa kí ohun ti àwa bá ńṣe lè so èso fún Ọlọ́run. Kíkún Ẹ̀mí kò ṣiṣẹ ní òde ara nìkan, ó tún ńṣiṣẹ́ nínú àwọn èrò àti èròngbà fún àwọn ìṣe wa náà. Orin Dafidi 19:14 sọ wípé, "Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi, àti àṣàrò ọkàn mi, kí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà li ojú rẹ, Olúwa, agbára mi, àti olùdáǹdè mi."
Ẹ̀ṣẹ̀ ni nǹkan náà tí ó máa ńdí kíkún ni pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́ lọ́wọ́, àti wípé ìgbọràn sí Ọlọ́run ni bí a ṣe ńmú kíkún pẹ̀lú Ẹ̀mí dúró. Ìwé Efesu 5:18 pàṣe wípé kí a kún fún Ẹ̀mí; ṣùgbọ́n, kìí ṣe gbìgbàdúrà fún kíkún fún Ẹ̀mí Mímọ́ ni ó ńmú kíkún náà ṣẹ. Ìgbọ́ràn wa sí àṣẹ Ọlọ́run nìkan ló ńgba òmìnira Ẹ̀mí láàyè láti ṣiṣẹ́ nínú wa. Nítorí àwa ṣì lè ní ẹ̀ṣẹ̀, kò ṣeé ṣe kí a kún fún Ẹ̀mí ní ìgbà gbogbo. Nígbàtí àwa bá dẹ́ṣẹ̀ kí àwa kí ó jẹ́wọ́ rẹ̀ ní kíákíá fún Ọlọ́run kí a si tún ìfarajìn sí kíkún fún Ẹ̀mí àti dídarí ti Ẹ̀mí ṣe.
English
Báwo ni mo ṣe le kún fún Ẹ̀mí Mímọ́?