settings icon
share icon
Ibeere

Èmi ti tú ìgbeyàwó mi ká. Ǹjẹ́ èmi lè tún ìgbeyàwó ṣe gẹ́gẹ́ bíi Bíbélì?

Idahun


Àwa máa ńsábà rí àwọn ìbéèrè bíi "Èmi ti tú ìgbeyàwó mi ká fún irú àti idí kan báyìí báyìí. Ǹjẹ́ èmi lè tún ìgbeyàwó ṣe?" "A ti tú ìgbeyàwó mi ká nígbà méji—àkọ́kọ́ fún panṣágà nípasẹ̀ ọkọ tàbí ìyàwó mi, ẹ̀kejì fún ìwà tí kò báramu. Èmi ńfẹ́ ọkùnrin kan ti a tú ìgbeyàwó rẹ̀ ká ní ìgbà mẹ́ta—àkọ́kọ́ fún ìwà tí kò báramu, ìkejì fún panṣágà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, ìkẹ́ta láti ọwọ́ ìyàwó rẹ̀. Ǹjẹ́ a lè jọ ṣe ìgbéyàwó papọ̀?" Àwọn ìbéèré bíi eléyìí jẹ́ èyí tí ó ṣòro gan-an láti dáhùn nítorí Bíbélì kò lọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nípa oríṣiríṣi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó lè wáyé fún tí tún ìgbéyàwó ṣe lẹ́hìn ìkọ̀sílẹ̀ kan.

Ohun tí àwa lè mọ̀ dájú ní wípé ó ṣì jẹ́ ètò ti Ọlọ́run fún tọkọtaya tí ó ti ṣe ìgbéyàwó láti dúró nínú ìgbéyàwó níwọ̀n ìgbà tí ọkọ àti ìyàwó méjèèjì bá ṣì wà láàyè (Jẹnẹsisi 2:24; Matteu 19:6). Ohun kan ṣoṣo ní pàtó tí ó fi ààyè gbà fún tí tún ìgbeyàwó ṣe lẹ́hìn tí tú ìgbeyàwó ká ni fún panṣágà (Matteu 19:9), ti eléyìí ṣì jẹ́ àríyànjiyàn láàrín àwọn Kristiẹni. Ohun míìrán tí o tún ṣeé ṣe ni jíjánijùsílẹ̀—nígbàti ọkọ tàbí ìyàwó tí kò gbàgbọ́ kan bá fi ọkọ tàbí ìyàwó tí ó gbàgbọ́ sílẹ̀ (1 Kọrinti 7:12-15). Àyọkà yìí, bí o tìlẹ́ jẹ́ wípé, kò sọ ní pàtó nípa tí tún ìgbéyàwó ṣe, ńsọ nípa dídúró nínú ìgbéyàwó kan. Ní àwọn ipò èyítí a lè fojúrí, ti ìbálòpọ̀, tàbí ìmọ̀lára ìlòkulò tí kò dára lé tó láti fa ìpínyà, ṣùgbọ́n Bíbélì kò sọ nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀nyìí ní ìwò ti ìkọ̀sílẹ̀ tàbí títún ìgbéyàwó ṣe.

Àwa mọ nípa àwọn ohun méjì dájúdájú. Ọlọ̀run kórìra ti tú ìgbeyàwó ká (Malaki 2:16), àti wípé Ọlọ́run jẹ́ aláàánú tí ó ńdáríjì. Gbogbo ìgbeyàwó tí a tú ká jẹ́ l'átàri ti ẹ̀ṣẹ̀, bóyá ní ipa ti ọkọ tàbí ìyàwó tàbí àwọn méjèèjì. Ǹjẹ́ Ọlọ́run ńdárí ti tú ìgbeyàwó ká jì? Pátápátá! Tí tú ìgbeyàwó ká kò kéré fún ìdáríjì, ju àwọn ẹ̀ṣẹ̀ míìrán. Ìdárìjì gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wà nìpa ìgbàgbọ̀ nínú Jésù Kristi (Matteu 26:28; Efesu 1:7). Bí Ọlọ́run bá ńdárí ẹ̀ṣẹ̀ tí tú ìgbeyàwó ká jì, ǹjẹ́ èyí túmọ̀ sí wípé o ni òmìnira láti tún ìgbéyàwó ṣe? Kò pọn dandan. Ọlọ́run á máa pe àwọn ènìyàn láti dúro ní àpọ́n (1 Korinti 7: 7-8). A kò gbọ́dọ̀ rí jíjẹ́ àpọ́n bíi ègún tàbí ìjìyà kan, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bíi àǹfàní láti sin Ọlọ̀run pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa (1 Kọrinti 7:32-36). Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa wípé, bí o tìlẹ̀ jẹ́ wípé, ó sàn láti ṣe ìgbéyàwó ju kí ara wọn máa gbóná pẹ̀lú èrò ìbálòpọ̀ ọkunrin ati obinrin (1 Kọrinti 7:9). Bóyá èyí ní ìgbà míìrán ṣeé múlọ sí tí tún ìgbéyàwó ṣe lẹ́hìn ti tú ìgbeyàwó kan ká.

Nítorí náà, ǹjẹ́ ìwọ lè tàbí ǹjẹ́ ìwọ gbọ́dọ̀ tún ìgbeyàwó ṣe? Àwa kò lè dáhùn ìbéèrè yẹn. Ní ìkẹhìn, èyí ńbẹ láàrin ìwọ, ẹni tí ó fẹ́fẹ́, àti, pàtàkì jùlọ, Ọlọ́run. Ìmọ̀ran kàn ṣoṣo tí àwa lè fi fún ọ ní láti gbàdúrà sí Ọlọ́run fún ọgbọ́n nípa ohun tí Òun yóò fẹ́ kí o ṣe (Jakọbu 1:5). Gbàdúrà pẹ̀lú ọkàn tí ó ṣí sílẹ̀ àti bíbi Olúwa yìí tọkantọkàn kí o fi òùngbẹ Rẹ̀ sí ọkàn rẹ (Orin Dafidi 37:4). Wá ìfẹ ti Olúwa yìí (Òwe 3:5-6) kí o sì tẹ̀lé ìdarí Rẹ̀.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Èmi ti tú ìgbeyàwó mi ká. Ǹjẹ́ èmi lè tún ìgbeyàwó ṣe gẹ́gẹ́ bíi Bíbélì?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries