settings icon
share icon
Ibeere

Kínni ìpele tí o yẹ fún wíwà ní tímọ́tímọ́ ṣáájú ìgbéyàwó?

Idahun


Efesu 5:3 sọ fún wa wípé, "Ṣugbọn àgbèrè, ati gbogbo ìwà èérí, tabi ojúkòkòrò... Bi o ti yẹ àwọn eniyan mímọ́." Ohunkóhun tí ó dà bí "àwọn ìgbúròó" ti ìwà àgbèrè jẹ́ èyí tí kò yẹ fún Kristiẹni kan. Bíbélì kò fún wa ní àkójọ àwọn ohun tí ó jẹ́ àmúyẹ gẹ́gẹ́ bíi "ìgbúròó" tàbì sọ fún wa àwọn iṣẹ́ tí a lè fojúrí tí a fọwọ́ sí fún tọkọtaya láti máa ṣe ṣáájú ìgbéyàwó. Ṣùgbọ́n, nítorí wípé Bíbélì kò sọ ní pàtó nípa ọ̀rọ̀ náà kò túmọ̀ sí wípé Ọlọ́run fí ọwọ́ "àwọn iṣe tí ó ńwá ṣáájú-ìbálòpọ̀" ṣáájú ìgbéyàwó. Ní pàtàkì eré-àkọ́ṣe ṣáájú ìbálòpọ̀ ní a gbékalẹ̀ láti gbaradì fún ìbálòpọ̀. Ní èrò ọlọ́gbọ́n lẹ́hìn náà, ere-àkọ́ṣe ṣáájú ìbálòpọ̀ kò gbọ́dọ̀ kọjá àárín àwọn tọkọtaya tí wọ́n ti ṣe ìgbéyàwó. Ohunkóhun tí ó lè kà sí ere-àkọṣe ṣáájú ìbálòpọ̀ ní a gbọ́dọ̀ yẹra fún títí di ìgbéyàwó.

Bí iyèméjì kan bá wà bóyá iṣẹ́ kan tọ́ fún tọkọtaya kan tí kò tìí ṣe ìgbéyàwó, kíi wọn yẹra fún (Romu 14:23). Ohunkóhun àti gbogbo ìbálòpọ̀ àti ere-àkọ́ṣe ṣáájú ìbálòpọ̀ kò gbọ́dọ̀ kọjá àárín àwọn tọkọtaya tí wọ́n ti ṣe ìgbéyàwó. Tọkọtaya tí kò tìí ṣe ìgbéyàwó gbọ́dọ̀ yẹra fún èyíkéyì iṣẹ́kíṣẹ́ tí ó ńdán wọn wò sí ìbálòpọ̀, èyí tí ó farajọ àìmọ́, tàbí èyí tí a lè pè ní ere-àkọ́ṣe ṣáájú ìbálòpọ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùṣọ̀-àgùntàn àti agbaninímọ̀ràn Kristiẹni gba ni lá mọ̀ràn gidigidi wìpé kí tọkọtaya má kọjá dídi ara wọn lọ́wọ́ mú, dídìmọ ara ẹni, àti ìfẹnukonu fẹ́rẹ́fẹ́ ṣáájú ìgbéyàwó. Ní ìwọn bí àwọn tọkótaya tí wọn ti ṣe ìgbéyàwó bá ṣe ńṣe àjọpín láàrin ara wọn, bẹ́ẹ̀ ní ìbáṣepọ̀ ìbálòpọ̀ náà yóò ṣe di pàtàkì àti èyí tí o dá yàtọ̀ nínú ìgbéyàwó yẹn.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni ìpele tí o yẹ fún wíwà ní tímọ́tímọ́ ṣáájú ìgbéyàwó?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries